Job 37:1-13

Job 37:1-13 YBCV

AIYA si fò mi si eyi pẹlu, o si ṣi kuro ni ipò rẹ̀. Fetisilẹ dãda, ki ẹ si gbọ́ iró ohùn rẹ̀, ati iró ti o ti ẹnu rẹ̀ jade wá. O ṣe ilana rẹ̀ nisalẹ abẹ ọrun gbogbo, manamana rẹ̀ ni o si jọwọ rẹ̀ lọwọ de opin ilẹ aiye. Lẹhin manamana ohùn kan fọ̀ ramuramu, o fi ohùn ọlanla rẹ̀ sán ãrá: on kì yio si da ãrá duro nigbati a ba ngbọ́ ohùn rẹ̀. Ọlọrun fi ohùn rẹ̀ sán ãrá iyanilẹnu, ohun nlanla ni iṣe ti awa kò le imọ̀. Nitoriti o wi fun ojo didì pe, Iwọ rọ̀ silẹ aiye, ati pẹlu fun ọwọ ojo, ati fun ojo nla agbara rẹ̀. O fi edidi di gbogbo enia, ki gbogbo wọn ki o le imọ̀ iṣẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn ẹranko iwọnu ihò lọ, nwọn a si wà ni ipò wọn. Lati iha gusu ni ìji ajayika ti ijade wá, ati otutu lati inu afẹfẹ ti tu awọsanma ká. Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì. Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká. Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ. O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu.