Job 37:1-13
Job 37:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
AIYA si fò mi si eyi pẹlu, o si ṣi kuro ni ipò rẹ̀. Fetisilẹ dãda, ki ẹ si gbọ́ iró ohùn rẹ̀, ati iró ti o ti ẹnu rẹ̀ jade wá. O ṣe ilana rẹ̀ nisalẹ abẹ ọrun gbogbo, manamana rẹ̀ ni o si jọwọ rẹ̀ lọwọ de opin ilẹ aiye. Lẹhin manamana ohùn kan fọ̀ ramuramu, o fi ohùn ọlanla rẹ̀ sán ãrá: on kì yio si da ãrá duro nigbati a ba ngbọ́ ohùn rẹ̀. Ọlọrun fi ohùn rẹ̀ sán ãrá iyanilẹnu, ohun nlanla ni iṣe ti awa kò le imọ̀. Nitoriti o wi fun ojo didì pe, Iwọ rọ̀ silẹ aiye, ati pẹlu fun ọwọ ojo, ati fun ojo nla agbara rẹ̀. O fi edidi di gbogbo enia, ki gbogbo wọn ki o le imọ̀ iṣẹ rẹ̀. Nigbana ni awọn ẹranko iwọnu ihò lọ, nwọn a si wà ni ipò wọn. Lati iha gusu ni ìji ajayika ti ijade wá, ati otutu lati inu afẹfẹ ti tu awọsanma ká. Nipa ẹmi Ọlọrun a fi ìdi-omi funni, ibu-omi a si sunkì. Pẹlupẹlu o fi omi pupọ mu awọsanma wuwo, a si tú awọsanma imọlẹ rẹ̀ ká. Awọn wọnyi ni a si yi kakiri nipa ilana rẹ̀, ki nwọn ki o le iṣe ohunkohun ti o pa fun wọn li aṣẹ loju aiye lori ilẹ. O mu u wá ibãṣe fun ikilọ̀ ni, tabi fun rere ilẹ rẹ̀, tabi fun ãnu.
Job 37:1-13 Yoruba Bible (YCE)
“Nígbà tí mo gbọ́, ọkàn mi wárìrì, ó sì fò sókè ní ipò rẹ̀. Gbọ́ ohùn rẹ̀ tí ń dún bí ààrá, ati ariwo tí ń ti ẹnu rẹ̀ jáde. Ó rán mànàmáná rẹ̀ sí wọn jákèjádò ojú ọ̀run, títí dé òpin ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn náà, a gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ ninu ọlá ńlá rẹ̀, bí ìgbà tí ààrá bá sán, sibẹsibẹ kò dá mànàmáná dúró bí àwọn eniyan ti ń gbóhùn rẹ̀. Ohùn Ọlọrun dún bí ààrá tìyanu-tìyanu, a kò lè rí ìdí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ó pàṣẹ pé kí yìnyín rọ̀ sórí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni òjò wẹliwẹli, ati ọ̀wààrà òjò. Ó ká gbogbo eniyan lọ́wọ́ iṣẹ́ kò, kí wọ́n lè mọ iṣẹ́ rẹ̀. Àwọn ẹranko wọ ihò wọn lọ, wọ́n dákẹ́ sibẹ, wọ́n sá pamọ́. Ìjì líle fẹ́ jáde láti inú yàrá rẹ̀, òtútù sì mú wá láti inú afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́. Yìnyín ti inú èémí Ọlọrun wá, gbogbo omi inú odò sì dì. Ó fi omi kún inú ìkùukùu, ìkùukùu sì fọ́n mànàmáná rẹ̀ ká. Wọ́n ń yípo lábẹ́ ìtọ́ni rẹ̀, láti mú gbogbo àṣẹ tí ó pa ṣẹ, lórí ilẹ̀ alààyè. Ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi ṣẹlẹ̀, bóyá fún àtúnṣe ni, tabi nítorí ilẹ̀ rẹ̀, tabi láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
Job 37:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Àyà sì fò mi sí èyí pẹ̀lú, ó sì kúrò ní ipò rẹ̀. Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá. Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé. Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná ohùn kan fọ̀ ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá. Òhun kì yóò sì dá àrá dúró, nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀. Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńláńlá ni í ṣe tí àwa kò le mọ̀. Nítorí tí ó wí fún yìnyín pé, ‘Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé,’ àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, ‘Fún òjò ńlá agbára rẹ̀.’ Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀, ó sì tún dá olúkúlùkù ènìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn. Láti ìhà gúúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọsánmọ̀ ká. Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì. Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn. Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.