Job 24:13-25

Job 24:13-25 YBCV

Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀. Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè. Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀. Li òkunkun nwọn a runlẹ wọle, ti nwọn ti fi oju sọ fun ara wọn li ọsan, nwọn kò mọ̀ imọlẹ. Nitoripe bi oru dudu ni owurọ̀ fun gbogbo wọn; nitoriti nwọn si mọ̀ ibẹru oru dudu. O yara lọ bi ẹni loju omi; ifibu ni ipin wọn li aiye, on kò rìn lọ mọ li ọ̀na ọgba-ajara. Ọdá ati õru ni imu omi ojo-didi gbẹ, bẹ̃ni isa-okú irun awọn ẹ̀lẹṣẹ. Inu ibímọ yio gbagbe rẹ̀, kokoro ni yio ma fi adun jẹun lara rẹ̀, a kì yio ranti rẹ̀ mọ́; bẹ̃ni a o si ṣẹ ìwa-buburu bi ẹni ṣẹ igi. Ẹniti o hù ìwa-buburu si agàn ti kò bí ri, ti kò ṣe rere si opó. O fi ipá rẹ̀ fà alagbara lọ pẹlu; o dide, kò si ẹniti ẹmi rẹ̀ da loju. On si fi ìwa ailewu fun u, ati ninu eyi ni a o si tì i lẹhin, oju rẹ̀ si wà ni ipa-ọna wọn. A gbe wọn lekè nigba diẹ, nwọn kọja lọ, a si rẹ̀ wọn silẹ, a si mu wọn kuro li ọ̀na, bi awọn ẹlomiran, a si ke wọn kuro bi ori ṣiri itú ọkà bàbà. Njẹ, bi kò ba ri bẹ̃ nisisiyi, tani yio mu mi li eké, ti yio si fi ọ̀rọ mi ṣe alainidi?