“A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀,
tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà.
Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde,
kí ó lè pa talaka ati aláìní,
a sì dàbí olè ní òru.
Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú,
ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’;
ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀.
Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri,
ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́,
wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí,
wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀.
Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn,
ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.”
Sofari dáhùn pé,
“O sọ wí pé,
‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá;
ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà,
ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́.
Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹ
bẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì.
Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú,
ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’
Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ,
wọn kò sì ṣe rere fún opó.
Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀;
wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn.
Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́,
ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn.
A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀,
lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀,
wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé,
a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà.
Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́,
kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.”