Job 24:13-25

Job 24:13-25 Yoruba Bible (YCE)

“A rí àwọn tí wọ́n kọ ìmọ́lẹ̀, tí wọn kò mọ ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró ní ọ̀nà náà. Bí ilẹ̀ bá ṣú, apànìyàn á dìde, kí ó lè pa talaka ati aláìní, a sì dàbí olè ní òru. Alágbèrè pàápàá ń ṣọ́ kí ilẹ̀ ṣú, ó ń wí pé, ‘Kò sí ẹni tí yóo rí mi’; ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. Lóru, wọn á máa lọ fọ́ ilé kiri, ṣugbọn bí ilẹ̀ bá ti mọ́, wọn á ti ìlẹ̀kùn mọ́rí, wọn kì í rí ìmọ́lẹ̀. Àárọ̀ ni òkùnkùn biribiri jẹ́ fún gbogbo wọn, ọ̀rẹ́ wọn ni òkùnkùn biribiri tí ó bani lẹ́rù.” Sofari dáhùn pé, “O sọ wí pé, ‘Ìṣàn omi a máa gbá àwọn ẹni ibi lọ kíákíá; ìpín tiwọn a sì di ìfibú ninu ilẹ̀ náà, ẹnikẹ́ni kìí sì í lọ sinu ọgbà àjàrà wọn láti ṣiṣẹ́ mọ́. Bí ọ̀gbẹlẹ̀ ati ooru ṣe máa ń mú kí omi yìnyín gbẹ bẹ́ẹ̀ ni ibojì ṣe ń gbé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ mì. Wọn á gbàgbé wọn láàrin ìlú, ẹnikẹ́ni kì í ranti orúkọ wọn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi ṣe é wó lulẹ̀ bí ìtì igi.’ Wọ́n ń jẹ oúnjẹ àgàn tí kò bímọ, wọn kò sì ṣe rere fún opó. Sibẹsibẹ Ọlọrun fi ẹ̀mí gígùn fún alágbára nípa agbára rẹ̀; wọn á gbéra nígbà tí ayé bá sú wọn. Ọlọrun ń dáàbò bò wọ́n, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì ń pa wọ́n mọ́ ni ọ̀nà wọn. A gbé wọn ga fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà, a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn á rọ, wọn á sì rẹ̀ dànù bí ewé, a ké wọn kúrò bí orí ọkà bàbà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnìkan já mi nírọ́, kí ó sì fi hàn pé ìsọkúsọ ni mò ń sọ.”

Job 24:13-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Àwọn ni ó wà nínú àwọn tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí ìmọ́lẹ̀; Wọn kò mọ̀ ipa ọ̀nà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dúró nípa ọ̀nà rẹ̀. Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè. Ojú alágbèrè pẹ̀lú dúró kí ilẹ̀ ṣú díẹ̀; ‘Ó ní, ojú ẹnìkan kì yóò rí mi,’ ó sì fi ìbòjú bojú rẹ̀. Ní òkùnkùn wọn á rúnlẹ̀ wọlé, tí wọ́n ti fi ojú sọ fún ara wọn ní ọ̀sán, wọn kò mọ̀ ìmọ́lẹ̀. Nítorí pé bí òru dúdú ní òwúrọ̀ fún gbogbo wọn; nítorí tí wọn sì mọ̀ ìbẹ̀rù òkùnkùn. “Ó yára lọ bí ẹni lójú omi; ìpín wọn ní ilé ayé ni a ó parun; òun kò rìn lọ mọ́ ní ọ̀nà ọgbà àjàrà. Gẹ́gẹ́ bi ọ̀dá àti òru ní í mú omi òjò-dídì yọ́, bẹ́ẹ̀ ní isà òkú í run àwọn tó dẹ́ṣẹ̀. Inú ìbímọ yóò gbàgbé rẹ̀, kòkòrò ní yóò máa fi adùn jẹun lára rẹ̀, a kì yóò rántí ènìyàn búburú mọ́; Bẹ́ẹ̀ ní a ó sì ṣẹ ìwà búburú bí ẹní ṣẹ́ igi; Ẹni tí o hù ìwà búburú sí àgàn tí kò ṣe rere sí opó. Ọlọ́run fi ipá agbára rẹ̀ fa alágbára, bí wọ́n tilẹ̀ fìdímúlẹ̀, kò sí ìrètí ìyè fún wọn. Ọlọ́run sì fi àìléwu fún un, àti nínú èyí ni a ó sì tì i lẹ́yìn, ojú rẹ̀ sì wà ní ipa ọ̀nà wọn. A gbé wọn lékè nígbà díẹ̀, wọ́n kọjá lọ; a sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; A sì mú wọn kúrò ní ọ̀nà bí àwọn ẹlòmíràn, a sì ké wọn kúrò bí orí síírí ọkà bàbà. “Ǹjẹ́, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ nísinsin yìí, ta ni yóò mú mi ní èké, tí yóò sì sọ ọ̀rọ̀ mi di aláìníláárí?”