Job 24:1-12

Job 24:1-12 YBCV

ẼṢE bi igba-igba kò pamọ lọdọ Olodumare; ti awọn ojulumọ rẹ̀ kò ri ọjọ rẹ̀? Nwọn a ṣi àmi àla ilẹ, nwọn a fi agbara ko agbo ẹran lọ, nwọn si bọ́ wọn. Nwọn a si dà kẹtẹkẹtẹ alainibaba lọ, nwọn a si gba ọdá-malu opó li ohun ògo. Nwọn a bì alaini kuro loju ọ̀na, awọn talaka aiye a sa pamọ́ pọ̀. Kiyesi i, bi kẹtẹkẹtẹ igbẹ ninu ijù ni nwọn ijade lọ si iṣẹ wọn; nwọn a tete dide lati wá ohun ọdẹ; ijù pese onjẹ fun wọn ati fun awọn ọmọ wọn. Olukuluku a si ṣa ọka onjẹ-ẹran rẹ̀ ninu oko, nwọn a si ká ọgba-ajara enia buburu. Nihoho ni nwọn ma sùn laini aṣọ, ti nwọn kò ni ibora ninu otutu. Ọwara ojo oke-nla si pa wọn, nwọn si lẹ̀mọ apata nitoriti kò si abo. Nwọn ja ọmọ-alainibaba kuro li ẹnu-ọmu, nwọn si gbà ohun ẹ̀ri li ọwọ talaka. Nwọn rìn kiri nihoho laili aṣọ, awọn ti ebi npa rẹrù ìdi-ọka. Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn. Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na.