Job 24:1-12

Job 24:1-12 Yoruba Bible (YCE)

“Kí ló dé tí Olodumare kò fi yan ọjọ́ ìdájọ́, kí àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n sì rí ọjọ́ náà? “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò, láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn, wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn. Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ, wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò. Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà, gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́. “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀, wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀. Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olóko wọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà. Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru, wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù. Òjò a pa wọ́n lórí òkè, wọn a máa rọ̀ mọ́ àpáta nítorí àìsí ààbò. (Àwọn kan ń já àwọn ọmọ aláìníbaba gbà lẹ́nu ọmú, wọ́n sì ń gba ọmọ ọwọ́ lọ́wọ́ àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.) Àwọn aláìní ń rìn kiri ní ìhòòhò láìrí aṣọ wọ̀; ebi ń pa wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtí ọkà ni wọ́n rù. Wọ́n ń fún òróró lára èso olifi tí ó wà ní oko ìkà, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọtí ni wọ́n ń pọn. Àwọn tí wọn ń kú lọ ń kérora ní ìgboro, àwọn tí a pa lára ń ké fún ìrànlọ́wọ́, ṣugbọn Ọlọrun kò fetísí adura wọn.

Job 24:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́? Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀? Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀, wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn. Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo. Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà, àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́. Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn, wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ; ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn. Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko, wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú. Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ, tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù. Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n, wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò. Wọ́n já ọmọ aláìní baba kúrò ní ẹnu ọmú, wọ́n sì gbà ọmọ tálákà nítorí gbèsè. Wọ́n rìn kiri ní ìhòhò láìní aṣọ; àwọn tí ebi ń pa rẹrù ìdì ọkà, Àwọn ẹni tí ń fún òróró nínú àgbàlá wọn, tí wọ́n sì ń tẹ ìfúntí àjàrà, síbẹ̀ òǹgbẹ sì ń gbẹ wọn. Àwọn ènìyàn ń kérora láti ìlú wá, ọkàn àwọn ẹni tí ó gbọgbẹ́ kígbe sókè fún ìrànlọ́wọ́ síbẹ̀ Ọlọ́run kò kíyèsi àṣìṣe náà.