Eks 4:27-31

Eks 4:27-31 YBCV

OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu. Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u. Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ: Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na. Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.