Eksodu 4:27-31

Eksodu 4:27-31 YCB

OLúWA sì sọ fún Aaroni pé, “Lọ sínú aginjù láti lọ pàdé Mose.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mose ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Ní ìgbà náà ni Mose sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti rán fún Aaroni àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Farao. Mose àti Aaroni pe gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ. Aaroni sọ ohun gbogbo tí OLúWA sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe iṣẹ́ ààmì náà ní ojú àwọn ènìyàn náà. Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé OLúWA ti bẹ àwọn ọmọ Israẹli wò àti pé OLúWA ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn Ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.