Eks 4

4
Ọlọrun Fún Mose ní Agbára Ìyanu
1MOSE si dahùn o si wipe, Ṣugbọn kiyesi i, nwọn ki yio gbà mi gbọ́, bẹ̃ni nwọn ki yio fetisi ohùn mi: nitoriti nwọn o wipe, OLUWA kò farahàn ọ.
2OLUWA si wi fun u pe, Kini wà li ọwọ́ rẹ nì? On si wipe, Ọpá ni.
3O si wi fun u pe, Sọ ọ si ilẹ. On si sọ ọ si ilẹ, o si di ejò; Mose si sá kuro niwaju rẹ̀.
4OLUWA si wi fun Mose pe, Nà ọwọ́ rẹ ki o si mú u ni ìru: (On si nà ọwọ́ rẹ̀, o si mú u, o si di ọpá si i li ọwọ́:)
5Ki nwọn ki o le gbàgbọ́ pe, OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakobu, li o farahàn ọ.
6OLUWA si tun wi fun u pe, Fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. O si fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀: nigbati o si fà a yọ jade, si kiyesi i, ọwọ́ rẹ̀ dẹ́tẹ̀, o fún bi ẹ̀gbọn owu.
7O si wipe, Tun fi ọwọ́ rẹ bọ̀ àiya rẹ. (O si tun fi ọwọ́ rẹ̀ bọ̀ àiya rẹ̀; o si fà a yọ jade li àiya rẹ̀; si kiyesi i, o si pada bọ̀ bi ẹran ara rẹ̀.)
8Yio si ṣe, bi nwọn kò ba gbà ọ gbọ́, ti nwọn kò si fetisi ohùn iṣẹ-àmi iṣaju, njẹ nwọn o gbà ohùn iṣẹ-àmi ikẹhin gbọ́.
9Yio si ṣe, bi nwọn kò ba si gbà àmi mejeji yi gbọ́ pẹlu, ti nwọn kò si fetisi ohùn rẹ, njẹ ki iwọ ki o bù ninu omi odò nì, ki o si dà a si iyangbẹ ilẹ: omi na ti iwọ bù ninu odò yio di ẹ̀jẹ ni iyangbẹ ilẹ.
10Mose si wi fun OLUWA pe, Oluwa, emi ki iṣe ẹni ọ̀rọ-sisọ nigba atijọ wá, tabi lati igbati o ti mbá iranṣẹ rẹ sọ̀rọ: ṣugbọn olohùn wuwo ni mi, ati alahọn wuwo.
11OLUWA si wi fun u pe, Tali o dá ẹnu enia? tabi tali o dá odi, tabi aditi, tabi ariran, tabi afọju? Emi OLUWA ha kọ́?
12Njẹ lọ nisisiyi, emi o si pẹlu ẹnu rẹ, emi o si kọ́ ọ li eyiti iwọ o wi.
13On si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, rán ẹniti iwọ o rán.
14Inu OLUWA si ru si Mose, o si wipe, Aaroni arakunrin rẹ ọmọ Lefi kò ha wà? Emi mọ̀ pe o le sọ̀rọ jọjọ. Ati pẹlu, kiyesi i, o si mbọ̀wá ipade rẹ: nigbati o ba si ri ọ, on o yọ̀ ninu ọkàn rẹ̀.
15Iwọ o si sọ̀rọ fun u, iwọ o si fi ọ̀rọ si i li ẹnu: emi o si pẹlu ẹnu rẹ, ati pẹlu ẹnu rẹ̀, emi o si kọ́ nyin li eyiti ẹnyin o ṣe.
16On ni yio si ma ṣe ogbifọ rẹ fun awọn enia: yio si ṣe, on o ma jẹ́ ẹnu fun ọ, iwọ o si ma jẹ́ bi Olọrun fun u.
17Iwọ o si mú ọpá yi li ọwọ́ rẹ, eyiti iwọ o ma fi ṣe iṣẹ-àmi.
Mose Pada Lọ sí Ijipti
18Mose si lọ, o si pada tọ̀ Jetro ana rẹ̀, o si wi fun u pe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki nlọ ki emi si pada tọ̀ awọn arakunrin mi ti o wà ni Egipti, ki emi ki o si wò bi nwọn wà li ãye sibẹ̀. Jetro si wi fun Mose pe, Mã lọ li alafia.
19OLUWA si wi fun Mose ni Midiani pe, Lọ, pada si Egipti: nitori gbogbo enia ti nwá ẹmi rẹ ti kú tán.
20Mose si mú aya rẹ̀ ati awọn ọmọ-ọkunrin rẹ̀, o si gbé wọn gùn kẹtẹkẹtẹ kan, o si pada si ilẹ Egipti: Mose si mú ọpá Ọlọrun na li ọwọ́ rẹ̀.
21OLUWA si wi fun Mose pe, Nigbati iwọ ba dé Egipti, kiyesi i ki iwọ ki o ṣe gbogbo iṣẹ-iyanu, ti mo filé ọ lọwọ, niwaju Farao, ṣugbọn emi o mu àiya rẹ̀ le, ti ki yio fi jẹ ki awọn enia na ki o lọ.
22Iwọ o si wi fun Farao pe, Bayi li OLUWA wi, Ọmọ mi ni Israeli, akọ́bi mi:
23Emi si ti wi fun ọ pe, Jẹ ki ọmọ mi ki o lọ, ki o le ma sìn mi; iwọ si ti kọ̀ lati jẹ ki o lọ: kiyesi i, emi o pa ọmọ rẹ, ani akọ́bi rẹ.
24O si ṣe li ọ̀na ninu ile-èro, li OLUWA pade rẹ̀, o si nwá ọ̀na lati pa a.
25Nigbana ni Sippora mú okuta mimú, o si kọ ọmọ rẹ̀ ni ilà abẹ, o si sọ ọ si ẹsẹ̀ Mose, o si wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ fun mi nitõtọ.
26Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ. Nigbana ni Sippora wipe, Ọkọ ẹlẹjẹ ni iwọ nitori ikọlà na.
27OLUWA si wi fun Aaroni pe, Lọ si ijù lọ ipade Mose. On si lọ, o si pade rẹ̀ li oke Ọlọrun, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.
28Mose si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o rán a fun Aaroni, ati gbogbo aṣẹ iṣẹ-àmi ti o fi fun u.
29Mose ati Aaroni si lọ, nwọn si kó gbogbo àgba awọn ọmọ Israeli jọ:
30Aaroni si sọ gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA ti sọ fun Mose, o si ṣe iṣẹ-àmi na li oju awọn enia na.
31Awọn enia na si gbàgbọ́: nigbati nwọn si gbọ́ pe, OLUWA ti bẹ̀ awọn ọmọ Israeli wò, ati pe o si ti ri ipọnju wọn, nigbana ni nwọn tẹ̀ ori wọn ba, nwọn si sìn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa