Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si.
Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi.
Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a.
Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì.
Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú:
O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia.
Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba,
Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ.
Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju.
Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ.
Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ.
Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ.
Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin:
Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose.
Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe;
Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.