“Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí. Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú. Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á. Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé,
‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’
Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé,
‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’
Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé,
‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’
Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín:
‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun!
Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín,
tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ”