Iṣe Apo 13:26-41

Iṣe Apo 13:26-41 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ará, ẹnyin ọmọ iran Abrahamu, ati ẹnyin ti o bẹ̀ru Ọlọrun, awa li a rán ọ̀rọ igbala yi si. Nitori awọn ti ngbe Jerusalemu, ati awọn olori wọn, nitoriti nwọn kò mọ̀ ọ, ati ọ̀rọ awọn woli, ti a nkà li ọjọjọ isimi, kò yé wọn, nwọn mu u ṣẹ ni didajọ rẹ̀ lẹbi. Ati bi nwọn kò tilẹ ti ri ọ̀ran iku si i, sibẹ nwọn rọ̀ Pilatu lati pa a. Bi nwọn si ti mu nkan gbogbo ṣẹ ti a ti kọwe nitori rẹ̀, nwọn si sọ ọ kalẹ kuro lori igi, nwọn si tẹ́ ẹ si ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú: O si farahàn li ọjọ pipọ fun awọn ti o ba a gòke lati Galili wá si Jerusalemu, awọn ti iṣe ẹlẹri rẹ̀ nisisiyi fun awọn enia. Awa si mu ihinrere wá fun nyin, ti ileri tí a ti ṣe fun awọn baba, Bi Ọlọrun ti mu eyi na ṣẹ fun awọn ọmọ wa, nigbati o ji Jesu dide; bi a si ti kọwe rẹ̀ ninu Psalmu keji pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ. Ati niti pe o ji i dide kuro ninu oku, ẹniti kì yio tun pada si ibajẹ mọ́, o wi bayi pe, Emi ó fun nyin ni ore mimọ́ Dafidi, ti o daju. Nitori o si wi ninu Psalmu miran pẹlu pe, Iwọ kì yio jẹ ki Ẹni Mimọ́ rẹ ri idibajẹ. Nitori lẹhin igba ti Dafidi sin iran rẹ̀ tan bi ifẹ Ọlọrun, o sùn, a si tẹ́ ẹ tì awọn baba rẹ̀, o si ri idibajẹ. Ṣugbọn ẹniti Ọlọrun ji dide kò ri idibajẹ. Njẹ ki o yé nyin, ará, pe nipasẹ ọkunrin yi li a nwasu idariji ẹ̀ṣẹ fun nyin: Ati nipa rẹ̀ li a ndá olukuluku ẹniti o gbagbọ lare kuro ninu ohun gbogbo, ti a kò le da nyin lare ninu ofin Mose. Nitorina ẹ kiyesara, ki eyi ti a ti sọ ninu iwe awọn woli ki o maṣe de ba nyin, pe; Ẹ wo o, ẹnyin ẹlẹgàn, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki a si fẹ nyin kù: nitori emi nṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, iṣẹ ti ẹnyin kò jẹ gbagbọ, bi ẹnikan tilẹ rohìn rẹ̀ fun nyin.

Iṣe Apo 13:26-41 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ̀yin arakunrin, ìran Abrahamu, ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sin Ọlọrun, àwa ni a rán iṣẹ́ ìgbàlà yìí sí. Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú. Láìjẹ́ pé wọ́n rí ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú, wọ́n ní kí Pilatu pa á. Nígbà tí wọ́n ti parí ohun gbogbo tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé yóo ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ láti orí igi agbelebu, wọ́n tẹ́ ẹ sinu ibojì. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú. Fún ọpọlọpọ ọjọ́ ni ó fi ara hàn fún àwọn tí wọ́n bá a wá sí Jerusalẹmu láti Galili. Àwọn ni ẹlẹ́rìí fún gbogbo eniyan pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé, ‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’ Ní ti pé ó jí i dìde kúrò ninu òkú, tí kò pada sí ipò ìdíbàjẹ́ mọ́, ohun tí ó sọ ni pé, ‘Èmi yóo fun yín ní ohun tí mo bá Dafidi pinnu.’ Bẹ́ẹ̀ ni ó tún sọ níbòmíràn pé, ‘O kò ní jẹ́ kí Ẹni ọ̀wọ̀ rẹ mọ ìdíbàjẹ́.’ Nítorí nígbà tí Dafidi ti sin ìran tirẹ̀ tán gẹ́gẹ́ bí ète Ọlọrun, ó sun oorun ikú, ó lọ bá àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ rà nílẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí Ọlọrun jí dìde kò ní ìrírí ìdíbàjẹ́. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kí ó hàn si yín pé nítorí ẹni yìí ni a ṣe ń waasu ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fun yín. Ọpẹ́lọpẹ́ ẹni yìí ni a fi dá gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ láre, àwọn tí Òfin Mose kò lè dá láre. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra kí ohun tí a kọ sílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii má baà dé ba yín: ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ó yà yín lẹ́nu, kí ẹ sì parun! Nítorí n óo ṣe iṣẹ́ kan ní àkókò yín, tí ẹ kò ní gbàgbọ́ bí ẹnìkan bá ròyìn rẹ̀ fun yín.’ ”

Iṣe Apo 13:26-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn. “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé: “ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’ Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’ Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé: “ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’ “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́. “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jesu yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín. Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mose. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé: “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù; nítorí èmi ó ṣe ohun kan ní ọjọ́ yín, tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́, bí a tilẹ̀ sọ fún yin.’ ”