OLUWA ní,
“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,
tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;
tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.
Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,
nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.
Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,
ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.