Jer 17:5-6
Jer 17:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bayi li Oluwa wi: Egbe ni fun ẹniti o gbẹkẹle enia, ti o fi ẹlẹran ara ṣe apá rẹ̀, ẹniti ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ Oluwa! Nitoripe yio dabi alaini ni aginju, ti kò si ri pe rere mbọ̀: ṣugbọn yio gbe ibi iyangbẹ ilẹ wọnni ni aginju, ilẹ iyọ̀ ti a kì igbe inu rẹ̀.
Jer 17:5-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní, “Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan, tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀; tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA. Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀, nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i. Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà, ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.
Jer 17:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni OLúWA wí: “Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn, tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara, àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ OLúWA Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá, kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé, yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù, ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.