YouVersion Logo
Search Icon

JAKỌBU 4

4
Bíbá Ayé Rẹ́
1Níbo ni ogun ti ń wá? Níbo ni ìjà sì ti ń wá sáàrin yín? Ṣebí nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ yín tí ó ń jagun ninu àwọn ẹ̀yà ara yín ni. 2Ẹ̀ ń fẹ́ nǹkankan, ọwọ́ yín kò sì tẹ̀ ẹ́; ẹ bá ń tìtorí rẹ̀ paniyan; ẹ̀ ń jowú nítorí nǹkankan, ọwọ́ yín kò bá ohun tí ẹ̀ ń jowú lé lórí, ẹ bá sọ ọ́ di ọ̀ràn ìjà ati ogun. Ọwọ́ yín kò tẹ ohun tí ẹ fẹ́ nítorí pé ẹ kò bèèrè lọ́dọ̀ Ọlọrun. 3Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín. 4Ẹ̀yin àgbèrè, ẹ kò mọ̀ pé ìbá ayé ṣọ̀rẹ́ níláti jẹ́ ìbá Ọlọrun ṣọ̀tá? Nítorí náà, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ti yàn láti jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun. 5Àbí ẹ rò pé lásán ni Ìwé Mímọ́ sọ pé, “Ẹ̀mí tí ó fi sinu wa ń jowú gidigidi lórí wa?” 6Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”#Òwe 3:34
7Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ àṣẹ Ọlọrun. Ẹ dojú ìjà kọ Èṣù, yóo sì sálọ kúrò lọ́dọ̀ yín. 8Ẹ súnmọ́ Ọlọrun, òun óo sì súnmọ́ yín. Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, ẹ jẹ́ kí ọkàn yín dá ṣáká, ẹ̀yin oníyèméjì. 9Ẹ jẹ́ kí ọkàn yín bàjẹ́, ẹ ṣọ̀fọ̀, ẹ sọkún; ẹ má rẹ́rìn-ín mọ́, ńṣe ni kí ẹ fajúro. Ẹ máa banújẹ́ dípò yíyọ̀ tí ẹ̀ ń yọ̀. 10Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Oluwa, yóo wá gbe yín ga.
Dídá Arakunrin Wa Lẹ́jọ́
11Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa arakunrin rẹ̀ tabi tí ó bá ń dá arakunrin rẹ̀ lẹ́jọ́ ń sọ̀rọ̀ àbùkù sí òfin, ó tún ń dá òfin lẹ́jọ́. Tí ó bá wá ń dá òfin lẹ́jọ́, ó sọ ara rẹ̀ di onídàájọ́ òfin dípò olùṣe ohun tí òfin wí. 12Ẹnìkan ṣoṣo ni ó fúnni lófin, tí ó jẹ́ onídàájọ́. Òun ni ẹni tí ó lè gba ẹ̀mí là, tí ó sì lè pa ẹ̀mí run; Ṣugbọn ìwọ, ta ni ọ́ tí o fi ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?
Ìkìlọ̀ nípa Fífọ́nnu
13Ẹ gbọ́ ná, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí pé, “Lónìí, tabi lọ́la, a óo lọ sí ibi báyìí, a óo ṣe ọdún kan níbẹ̀; a óo ṣòwò, a óo sì jèrè.”#Ọgb 2:4; 5:9-13 14Ẹ kò mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín, tí ó wà fún àkókò díẹ̀, lẹ́yìn náà tí kò ní sí mọ́.#Òwe 27:1 15Ohun tí ẹ̀ bá máa wí ni pé “Bí Oluwa bá dá ẹ̀mí sí, a óo ṣe báyìí báyìí.” 16Ṣugbọn ẹ̀ ń lérí, ẹ̀ ń fọ́nnu; irú ìlérí báyìí kò dára.
17Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.

Currently Selected:

JAKỌBU 4: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy