YouVersion Logo
Search Icon

JAKỌBU 3

3
Ahọ́n
1Ẹ̀yin ará mi, kí ọpọlọpọ yín má máa jìjàdù láti jẹ́ olùkọ́ni, kí ẹ mọ̀ pé ìdájọ́ ti àwa olùkọ́ni yóo le. 2Nítorí gbogbo wa ni à ń ṣe àṣìṣe ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnikẹ́ni bá wà tí kò ṣi ọ̀rọ̀ sọ rí, a jẹ́ pé olúwarẹ̀ pé, ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ níjàánu.#Sir 5:9-15; 14:1; 28:13-26 3Tí a bá fi ìjánu sí ẹṣin lẹ́nu, kí wọ́n lè ṣe bí a ti fẹ́, a máa darí gbogbo ara wọn bí a bá ti fẹ́. 4Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo àwọn ọkọ̀ ojú omi. Bí wọ́n ti tóbi tó, tí ó jẹ́ pé afẹ́fẹ́ líle ní ń gbé wọn kiri, sibẹ ìtukọ̀ kékeré ni ọ̀gá àwọn atukọ̀ fi ń darí wọn sí ibi tí ó bá fẹ́. 5Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n, ẹ̀yà ara kékeré ni, ṣugbọn ìhàlẹ̀ rẹ̀ pọ̀.
Ẹ wo bírà tí iná kékeré lè dá ninu igbó ńlá! 6Iná ni ahọ́n. Ó kún fún àwọn nǹkan burúkú ayé yìí. Ninu àwọn ẹ̀yà ara wa, ahọ́n ni ó ń kó nǹkan ibi bá gbogbo ara. A máa mú kí gbogbo ara wá gbóná, iná ọ̀run àpáàdì ni ó túbọ̀ ń fún un ní agbára.#Sir 5:13; 28:22 7Gbogbo ẹ̀dá pátá: ati ẹranko ni, ati ẹyẹ, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà, ati àwọn ẹran omi, gbogbo wọn ni eniyan lè so lójú rọ̀. 8Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó kápá ahọ́n. Nǹkan burúkú tí ó kanpá ni, ó kún fún oró tí ó lè paniyan kíákíá. 9Ahọ́n ni a fi ń yin Oluwa ati Baba. Òun kan náà ni a fi ń ṣépè fún eniyan tí a dá ní àwòrán Ọlọrun.#Jẹn 1:26 10Láti inú ẹnu kan náà ni ìyìn ati èpè ti ń jáde. Ẹ̀yin ará mi, kò yẹ kí èyí rí bẹ́ẹ̀. 11Ǹjẹ́ omi dídùn ati omi kíkorò lè ti inú orísun omi kan náà jáde? 12Ẹ̀yin ará mi, ṣé igi ọ̀pọ̀tọ́ lè so èso olifi, tabi kí àjàrà kó so ọ̀pọ̀tọ́? Ìsun omi kíkorò kò lè mú omi dídùn jáde.
Ọgbọ́n láti Òkè Wá
13Ẹnikẹ́ni wà láàrin yín tí ó gbọ́n, tí ó tún mòye? Kí ó fihàn nípa ìgbé-ayé rere ati ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí ó fi ọgbọ́n hàn.#Sir 19:20-30 14Ṣugbọn tí ẹ bá ń jowú ara yín kíkankíkan, tí ẹ ní ọkàn ìmọ-tara-ẹni-nìkan, ẹ má máa gbéraga, kí ẹ má sì purọ́ mọ́. 15Èyí kì í ṣe ọgbọ́n tí ó wá láti òkè, ọgbọ́n ayé ni, gẹ́gẹ́ bíi ti ẹran-ara, ati ti ẹ̀mí burúkú. 16Níbi tí owú ati ìlara bá wà, ìrúkèrúdò ati oríṣìíríṣìí ìwà burúkú a máa wà níbẹ̀. 17Ṣugbọn ní àkọ́kọ́, ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ pípé, lẹ́yìn náà a máa mú alaafia wá, a máa ṣe ẹ̀tọ́, a máa ro ọ̀rọ̀ dáradára, a máa ṣàánú; a máa so èso rere, kì í ṣe ẹnu meji, kì í ṣe àgàbàgebè. 18Àwọn tí wọn bá ń fúnrúgbìn ire pẹlu alaafia yóo kórè alaafia.

Currently Selected:

JAKỌBU 3: YCE

Highlight

Share

Copy

None

Want to have your highlights saved across all your devices? Sign up or sign in

YouVersion uses cookies to personalize your experience. By using our website, you accept our use of cookies as described in our Privacy Policy