Ẹ̀bùn KérésìmesìÀpẹrẹ

The Gift of Christmas

Ọjọ́ 2 nínú 4

Bí Ìràwọ̀ Náà Ṣe Jáde Wá

Bíbélì sọ wí pé ọrùn oun ayé ń sọ ògo Ọlọ́run. Mo ní èrò wí pé gbogbo àwọn onígbàgbọ́ ni ó fi ara mọ eléyìí. Síbẹ̀síbẹ̀, ǹkánkán nípa Ìsẹ̀dá jẹ́ kí gbogbo ènìyàn sọ pé "Ó GÁ Ó"

Fún àwọn ènìyàn díẹ̀, ó lè jẹ́ òkè ńlá ní àwọ̀ sánmọ̀. Fún àwọn ẹlòmíràn, ìgbì omi okun tí ó ní àwọ̀ búlúù tí ó ń bì káàkiri tàbí àwọn àkójọpọ̀ tí ó mú oríṣiríṣi àwọ̀ èwe awọn igi jáde ní Ìgbà Ìrẹ̀dànù Èwe. Ṣùgbọ́n, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, ó jẹ́ ẹwà àti ogunlọ́gọ̀ àwọn ìràwọ̀ ni ojú ọrùn ni àṣálẹ́. Awọn ìtànṣán iná dídán àìníye ni a rí láti irú ọ̀nà jíjìn wá. Bí ó ti ṣe tóbi sì, ooru, àti bí ó ṣe pọ̀ sí jẹ́ ohun tí ó ní agbára púpọ̀ láti ronú nípa rẹ.

Ìràwọ̀ kan wà tí ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn tí ó kú. Ó jẹ́ ìràwọ̀ tí ó ṣe atọ̀nà àwọn amòye dé ọ̀dọ̀ Jésù. Ìtàn ìràwọ̀ yìí jẹ́ ohun tí ó ní àpẹẹrẹ. Ó bẹ́ẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí a pè ní amòye. Wọn wá “láti ìlà òòrùn,” o ṣee ṣé jù lọ l'áti Páṣíà. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyíi ni a mọ̀ sí àwọn ọba àti àwọn amòye, ọ̀rọ̀ náà Magi sì fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn méjèèjì jẹ́ ikan náà. Wọ́n jẹ́ ènìyàn tí ó ní ẹ̀kọ́ gíga tí wọn ṣiṣẹ́ de àwọn ipò àṣẹ nítorí bí ọgbọ̀n wọn ṣe pọ̀ tọ́.

Àwọn amòye wọ̀nyí ṣe àkíyèsí ìràwọ̀ túntún àti oríṣiríṣi míràn ní ojú ọ̀run ní àṣálẹ́ náà. Ohùn kan wà tí ó yàtọ̀ nípa ìràwọ̀ yẹn pàtó, wọ́n sì gbàgbọ́ pé ó ṣe àfihàn wí pé ọba ńlá kan tí de. Wọ́n pinnu l'áti tẹ̀lé ìràwọ̀ náà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rò pé yóò mú wọn lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ńlá yìí.

Ìràwọ̀ náà ṣe amọ̀nà wọn lọ sí ibi tí ọmọdékùnrin Jesu náà wa, àwọn amòye náà si jọ́sìn fún-Un, wọ́n fún-Un ní àwọn ẹ̀bùn pẹ̀lú. Ó dájú pé kò sí ìwúrí kan fún wọn nípa Màríà, Jósẹ́fù, Jésù àti àwọn àyíká wọn. Kò sí ohun tí ó tọ́ká sì wí pé ọba kan ti dé. Kò sí ìtẹ́, aṣọ ìṣàkóso, ààfin, tàbí àwọn ìránṣẹ́ rárá.

Wọ́n jẹ́ ìdílé onírẹ̀lẹ̀ ní agbègbè tí ó jẹ́ ìrẹ̀lẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn amòye kò lọ́ra láti tẹ́ ọwọ́ gba Jésù ọmọ jòjòló gẹ́gẹ́ bíi Ọba tí ó yẹ kí wọ́n máa bu ọlá fún. Wọ́n wólẹ̀ ní iwájú Rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀bùn olówó ńlá fún-Un. Gbogbo eléyìí dá l'órí ìràwọ̀ náà.

Ìràwọ̀ ni orísun ìtọ́sọ́nà fún àwọn amòye wọ̀nyí. Ó jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn nínú òkùnkùn.” Kì í ṣe pé ó wà nínú òkùnkùn ojú ọ̀run ní òru nìkan ni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ìṣípayá tí ó fi òtítọ́ ẹni tí Jésù jẹ́ àti ẹni tí Òun í ṣe hàn. Jésù ni Ọba tí àwọn ọba mìíràn ń tẹrí ba ní iwájú Rẹ̀ tí wọ́n sì ń jọ́sìn fún. Àwọn kan yóò ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú tinútinú, ní mímọ ẹni tí Ó jẹ́, ní igbà tí àwọn mìíràn yóò ṣe é ní abẹ́ àfipámúṣe àṣẹ Rẹ̀ bí wọ́n ti dúró ní iwájú ìdájọ́ Rẹ̀ ní ọjọ́ kan.

Àní ní òní yìí, ìràwọ̀ náà ń bá wa sọ̀rọ̀ síbẹ̀. Ó jẹ́ ìránilétí pé a ní ìwàláàyè Rẹ̀ pẹ̀lú wa tí ń tọ́ wa sí ọ̀nà tí ó sì ń fi òtítọ́ Ọlọ́run hàn wá. Kì í ṣe ìràwọ̀ ojú ọ̀run mọ́ bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́ tí a ti fi fún ni láti máà gbé inú wa. Òun ni "Ẹmi Otitọ, tí o ń tọ wá sí inú òtítọ́ gbogbo." Òun ni “olùdámọ̀ràn,” ẹni tí ó wà níbẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ sí èrò inú àti ẹ̀mí wa. Ó tan ìmọ́lẹ̀ kí a lè rìn láì sí ewu.

Gẹ́gẹ́ bí ìràwọ̀ ṣe jẹ́ ojúlówó àgbàyanu fún àwọn amòye, tí ó ń darí gbogbo ìṣísẹ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ fún ara rẹ̀ ti ń tọ́ wa sí ọ̀nà. Ìwé Òwe 3:5-6 sọ dáadáa pé, "Gbẹ́kẹ̀lé Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, má ṣe sinmi lé òye ara à rẹ; Mọ̀ Ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ Òun yóò sì máa tọ́ ipa ọ̀nà rẹ".

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Gift of Christmas

Kérésìmesì jẹ́ àkókò láti ṣe ayẹyẹ ẹ̀bùn tí ó ga jù lọ -Jésù Kristì. Tí a bá wo ìtàn nípa bí wọ́n ṣe ń retí pé kí Kristi dé ní ọjọ́ Kérésìmesì, ó máa ń rán wa l'étí pé Jésù wá láti jẹ́ ìmúṣẹ àwọn ìlérí àti ìdúróṣinṣin Ọlọ́run. Ní iwájú Jésù, Ìmánúẹ́lì, Ọlọ́run ńbẹ pẹ̀lú wa, ni ìrètí wa tí ń di ìmúṣẹ, tí àdúrà wa sì ti ń gbà.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ International Leadership Institute fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: https://iliteam.org