Ẹ̀bùn KérésìmesìÀpẹrẹ

Wíwàláàyè àwọn Ángẹ́lì
Àwọn áńgẹ́lì ṣe pàtàkì gan-an nínú ìtàn Kérésìmesì. Wọ́n máa ń fi ara hàn ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n sì máa ń kó ipa pàtàkì nínú ipò tí wọ́n bá wà. A mọ̀ wọ́n sí "àwọn ẹ̀mí tí ń ṣe ìránṣẹ́" àti "àwọn oníṣẹ́ Ọlọ́run", wọ́n sì kó ipa pàtàkì nínú ìtàn ìbí Jésù.
Nínú ìtàn Kérésìmesì, wọ́n jẹ́ "oníwàásù". Iṣẹ́ wọn ni láti kéde tàbí láti sọ ohun pàtàkì kan. Wọ́n ń ṣe èyí ní ìgbàkúùgbà nínú ìtàn ìbí i Jésù
Ìgbà àkọ́kọ́ ni ìgbà tí ángẹ́lì wá sí ọ̀dọ̀ Zacharias, ó sọ fún-un pé aya rẹ̀, Elizabeth, yíò bí ọmọ kan tí yíò síwájú Mèsáyà wá sí ayé. Lẹ́yìn èyí, ángẹ́lì kan wá sí odo Maria ó sì sọ fún-un pé bí ò tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ wúndíá, yíò bí Jésù, ọmọ Olọ́run.
Ohun tí ó tún ṣẹlẹ̀ ni pé ní ìgbà tí Jósẹ́fù rí i pé Màríà ti ní oyún, ọkàn rẹ̀ dàrú, ó sì pinnu láti fi òpin sí àjọṣe wọn ní po kùtù. Ní ìkẹyìn, áńgẹ́lì náà sọ fún Jósẹ́fù pé iṣẹ́ ìyanu ni Màríà fi ní oyún, àti pé ọmọ náà tí yíò bí jẹ́ Ọlọ́run tí ó gbé ara ènìyàn wọ̀. Ángẹ́lì náà tún wá fi kún-un pé ọmọ yìí yíò jẹ́ Olùgbàlà aráyé.
Ìtàn àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n ń tọ́jú agbo ẹran wọn ní òru tún wà. Ní ẹ̀ẹ̀kan sí i, áńgẹ́lì náà tún wá "mú ìhìn rere ayọ̀ ńláǹlà wá fún wọn". Ní ìgbà yìí, "ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run" wà pẹ̀lú áńgẹ́lì kan ṣoṣo tí ó ń polongo ìhìn rere náà.
Ní ìkẹyìn, áńgẹ́lì kan kìlọ̀ fún Jósẹ́fù nínú àlá pé kí ó mú Màríà àti Jésù kí wọ́n sì "sá lọ sí Íjíbítì" nítorí pé Hẹ́rọ́dù ń wá Jésù láti pa á. Nínú gbogbo ìtàn Kérésìmesì tí ó wà nínú Bíbélì, àwọn áńgẹ́lì wá, wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì darí ọ̀rọ̀ wọn sí Jésù.
Àwọn áńgẹ́lì ṣì wà, wọ́n sì ní iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, sùgbọ́n a ti fún wa ní àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà láti jẹ́ àwọn tí ó ń kéde "Ìhìn Rere" náà ní òní yìí. Àwa ni Ọlọ́run fi iṣẹ́ sísọ ìhìn rere ìfẹ́ tí ó wà nínú Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, fún àwọn ènìyàn. Ọdún Kérésìmesì jẹ́ àkókò tí ó dára láti ṣe ìpolongo Ìhìn Rere. A gba ìtọ́ni pé kí a lọ sọ ìhìn àgbàyanu nípa ìrètí àti ìgbàlà tí ó wà nínú Jésù Kristi fún gbogbo ènìyàn.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn ángẹ́lì ló ṣe èyí ní ìgbà Kérésìmesì àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, àwa ni a wà ní ìdìí rẹ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Kérésìmesì jẹ́ àkókò láti ṣe ayẹyẹ ẹ̀bùn tí ó ga jù lọ -Jésù Kristì. Tí a bá wo ìtàn nípa bí wọ́n ṣe ń retí pé kí Kristi dé ní ọjọ́ Kérésìmesì, ó máa ń rán wa l'étí pé Jésù wá láti jẹ́ ìmúṣẹ àwọn ìlérí àti ìdúróṣinṣin Ọlọ́run. Ní iwájú Jésù, Ìmánúẹ́lì, Ọlọ́run ńbẹ pẹ̀lú wa, ni ìrètí wa tí ń di ìmúṣẹ, tí àdúrà wa sì ti ń gbà.
More