Ìhámọ́ra Ọlọ́runÀpẹrẹ

The Armor of God

Ọjọ́ 5 nínú 5

A ṣàlàyé ìgbàgbọ́ pẹ̀lú ìtumò tó rọrùn yìí: ṣíṣe bíi wípé Ọlọ́run ń sọ òtítọ́.

Òtítọ́ jẹ́ òpó tí ìgbésí ayé ìsinmi àti ìgbàgbọ́ wa ní kíkún dá lórí. Tí o kò bá mọ òtítọ́, o kò lè mọ bí o máa se hùwà ni ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Torí náà òtító èèyàn Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pèsè òpómúléró tó fún ìgbàgbọ́ wa láyè láti gbèrú àti gbilẹ̀.

Òtító Ọlọ́run ní ohun tó mú ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run yìí tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Láìsí òtítọ́, a kò ní ìpìlẹ̀ tó dúró sán-ún láti gbé asà ìgbàgbọ́ wa kọ́ lé lórí. Torí náà mímọ òtítọ́ Ọlọ́run àti òtítọ́ nípa Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí a se fi hàn nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ṣe pàtàkì gan tí a bá fẹ́ lo ìgbàgbọ́ wa lọ́nà tó yẹ, àti nírírí àwọn àǹfààní tó wà lábẹ́ ìdáàbòbo àwọn asà wa.

Èyíkéyìí ìjíròrò lórí ìgbàgbọ́ yóò jẹ́ àìpé láìsí àlàyé nípa kókó pàtàkì gbígbó ohùn Ọlọ́run ni kedere àti ní pípé.


Tí a kò bá ṣọ́ra, ìgbàgbọ́ lè rọrùn láti tètè yí dà òmùgò—aláìlọ́gbọ́n, áìni ìronújinlẹ̀, kódà wàdùwàdù àti léwu, ìwà tí a se ni orúkọ ìgbàgbọ́. Àmọ́ nígbà gbogbo ní a gbọ́dọ̀ kọ́ ìgbàgbọ́ òtítọ́ origun mẹ́rin lórí ìpìlè Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti a kọ̀ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣé dárí e láti fisí lò ní ayé è. Báwo ni o máa ṣàpèjúwe ìyàtọ̀ láàárín ìgbàgbọ́ àti asiwère? Kí ni o mú ni yẹra fún kikiọjá ààlà láàárín àwọn méjèèjì?

Gẹ́gẹ́ onígbàgbó, a ní àǹfààní tí mimò ìtọ́sọ́nà Rè fún wa bí a ń ṣe fi àdúrà wá a. Òun yóò jẹ́ olódodo láti fi òtítọ́ hàn wa, láti fi ìtọ́sọ́nà È fún ìgbése tó kàn tí o yẹ kí a gbé hàn wa. Kódà, wíwà ní ìdánilójú àti ìtẹnumọ́ ni ìgbése tọ́ kàn se pàtàkì kí a bàa lè wà déédéé bí a ń se lépa ìgbé ayé tó ní ìdáàbòbo látọ́wọ́ asà ìgbàgbọ́ wa.

Níwọ̀n bí o bá mò òtítọ́ Ọlọ́run kedere tàbí ìlérí Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ tí a ń sọ̀rọ̀ lé lórí, àkókò tí tó láti tè síwájú ni ònà ìṣọ̀kan pèlú e. Fetí sílè dáradára —àwọn ìmọ̀lára rè won kò lè jẹ́ nǹkan tó má se ìpinnu ìkẹyìn fún àwọn ìse rè láé. Àwọn ìmọ̀lára lè yípadà àtipe wọn wà lábẹ́ ìtẹríba sí ìmọ̀lára tí òde ara. Àwọn ìse tí a bá ń se nínú ìgbàgbọ́ gbọ́dọ̀ ni ìdákọ̀ró nínú nǹkan tó ni ìpìlẹ̀ tó dúró sán-ún àti fidí múlẹ̀.

Ọlọ́run wa Jé òtítọ́ àti pé Òun ló yé láti tè lé.

O wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo —tayọ jìnnà gan jù Èṣù nínú okun—láti gbó àdúrà wàhálà wa, fún wa ní àwọn ìlérí aláìbẹ̀rù Rè, àti ìgbé kalẹ̀ ìmọ́lè tó kàn tí a nílò láti rìn láìyẹsẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà Rè. E gbé àwọn asà yín sókè, èyín akíkanjú ọmọ ogun. A ń rìn nípa ìgbàgbọ́.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Armor of God

Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Priscilla Shirer àti ẹgbẹ́ ẹ Lifeway Christian Resources fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.lifeway.com