Ìhámọ́ra Ọlọ́runÀpẹrẹ

The Armor of God

Ọjọ́ 2 nínú 5

Pọ́ọ̀lù kò bèbè nínú àdúrà pé kí àwọn onígbàgbọ́ Éfésù gbá ohun ìní wọn lọ́pò yanturu bíi ọrọ̀ tí èmí, àwọn ìbùkún, agbára, àti àṣẹ, àmọ́ pé kí wọ́n lè mọ̀ pé ti wọn ló jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, wọ́n ti gba àwọn ohun wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti ní àwọn ǹkan wọ̀nyí. Àmọ́ láì ṣe pé wọ́n mọ àwọn ǹkan yìí, kíni ìwúlò gbogbo rẹ̀.

Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, ìhámọ́ra èmí tó ń ṣe àpèjúwèé rẹ̀ nínú Éfésù 6 kàn jẹ́ àsọtúnsọ—ọ̀nà tó yàtò láti ṣàpèjúwe—ohun tí Pọ́ọ̀lù tí n ṣàlàyé ni apá àkọ́kọ́ létà náà. Báwo ni wọn má se “wò” tàbí “mú ” àwọn ohun tí wọn kò mọ̀ pé àwọn ni? Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ fún wọn ni—Ìgbése àkọ́kọ́ fún wa—ni lílo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ti ẹ́mí tí a ti fún wa ni láti ní ojú ẹ̀mí tí ó ṣí sílẹ̀ kí a lè rí wọn.

Ìtàn Èlíṣà àti ìránṣẹ́ rẹ̀ tí o ni ojú síṣú ni Àwọn Ọba Kejì 6 ni òkan lára àwọn ìtàn ti mo fẹ́ràn jù lo nínú in Bíbélì. Ìtàn náà dá lóríi ìjàkadì tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ láàrin ọba Árámù tó ń bínú àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.

Ojú ìránṣẹ́ Èlíṣà kún. Lákọ́kọ́, o kan lè rí àwọn ọ̀tá, o ṣeé ṣe kí èyí ti filè pẹ̀lú ìdáhùnpadà mìíràn tí kò jù ìbẹ̀rù àti àníyàn ṣíṣe lo.

Àmọ́ nígbà náà ló yípadà sí òtítọ́ ti ẹ̀mí: òpò sí ń mbè ni lárọ̀ọ́wọ́tó rè àti sí ń ṣíṣe nítorí è jù bí o ti lè lérò lo láé. Ohun tí ojú ti ara rẹ̀ lè rí wọn kò jẹ́ ìfagagbága fún àwọn ohun tí o kò lè rí. Àdúrà Èlíṣà ràn a lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ó mọ̀ gbogbo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àti okun ní ipa tirẹ̀ nígbà tí ó ń jà lòdì sí àwọn ọ̀tá.

Láti je onídánilójú àti olúṣẹ́gun, o ní láti “rí ” i.
Ni Éfésù 1, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ apá ibi ẹ̀bùn díẹ̀ ti Ọlọ́run ti fún wa. Òpò yín mbè, àti pé oókan kan sopọ̀ lọ́nà àkànṣe pẹ̀lú ìhámọ́ra àti àwọn ohun ìjà tí èmí rè. Kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ láti lóye bí gbogbo won se bá ìṣètò ara wọn mu sínú ipá láti bàa lè fẹ̀yìn ọ̀tá balẹ̀ ni ìran. O kò lè lo wọn tí o kò bá dá wọn mò délẹ̀délẹ̀, tí o kò bá mò nípa wíwà lárọ̀ọ́wọ́tó àti jíjẹ pàtàkì won ni siṣàṣeyọrí ni wọ̀yá ìjà pẹ̀lú ọ̀tá.

Ìségun bẹ̀rẹ̀ níhìn-ín. O bẹ̀rẹ̀ lónìí. O bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà fún ìran.

Torí náà dára pò mo Pọ́ọ̀lù ni bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run láti túbọ̀ ṣí ojú rẹ ní kíkún kì se pé kí o bá lè rí iṣẹ́ ọ̀tá nìkan, àmọ́ o lè tún mọ ilẹ̀kùn rere nípa ohun ti Ọlọ́run ti fún ọ láti tú ohun ìjà ọ̀tá sílẹ̀ àti ségun rẹ̀ nínú ayé è.

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

The Armor of God

Ní gbogbo ọjọ́, lójoojúmó, àwọn ogun àìrí njà ní àyíká rẹ - àìrí, àìgbọ́, sùgbón o ń ríi ipà rẹ ẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà nínú ayé è rẹ. Àwọn ọmọ ogun èṣù ńwá ònà láti ṣe búburú nínú gbogbo ohun tí ó ṣe pàtàkì ṣí ọ: ọkàn rẹ, èèrò rẹ, ìgbéyàwó rẹ ẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìbáṣepọ̀ rẹ, àwọn ohun tí o nla kàkà fún, àlá à rẹ, ọjọ́ iwájú rẹ̀ ẹ. Sùgbón èrò ìjà a rẹ dúró lóri pé kí ó ká ọ mọ́ láì ro àti lái gbaradi. Bí àtì kiri yìí àti bí ó ṣe ká ọ mọ́ láì gbaradi yìí bá ti su o, ètò yìí wà fún ọ. Ọ̀tá yìí má n kùnà pátápátá tí ó bá pàdé Obìnrín tí o gbaradi. Ìhámọ́ra Ọlọrun ju àlàyé Bíbélì lásán nípa ohun èlò tí onígbagbọ ní, o jẹ́ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti wọ̀ ọ́, àti kíkọ́ ọna bi a o se yori funrarawa.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Priscilla Shirer àti ẹgbẹ́ ẹ Lifeway Christian Resources fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: www.lifeway.com