Àṣàrò Nípa KérésìmesìÀpẹrẹ

Ọlọ́run Yàn
Ìtàn Kérésìmesì wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkéde áńgẹ́lì fún Màríà, ó sì parí pẹ̀lú ìbẹ̀wò àwọn amòye. Èmi yóò máa tọ́ka sí Lúùkù jù lọ nínú àwọn àyẹ̀wò àti ìmúlò ti Ìtàn Kérésìmesì wọ̀nyí, nítorí àkọsílẹ̀ tirẹ̀ ni ó jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ jù lọ nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìhìnrere.
Ò jẹ́ ní ìgbà kan náà, ìtàn ti ara ẹni àti ìkọ̀kọ̀, síbẹ̀síbẹ̀, ti gbangba, àti ìyàlẹ́nu.
Àwọn òṣèré ènìyàn tí ó kún ìtàn náà jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin Júù; áńgẹ́lì ògbó kan, Gabrieli; Josefu; àwọn olùṣọ́-àgùtàn agbègbè; pẹ̀lú àwọn amòye láti ìla-òòrùn. A kò tíì rí irúfẹ́ àkọ́jọpọ̀ àwọn òṣèré béè rí, a kò sì tíì rí i láti ìgbà náà. Eré tí a ṣe jáde ní àbájáde fún àgbáálá ayé, kì í ṣe ti àdúgbò lásán.
Ní ọdún kọ̀ọ̀kan ni a sọ Ìtàn Kérésìmesì ní ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà, ní àwọn miliọnu agbègbè. Ó jẹ́ bíi ọmọ ní àfilọ̀ àti ayédèrọ̀, ọlọ́rọ̀ àti ògbó ní àwọn òfin ẹ̀kọ́ Olọ́run, ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ní ìfẹ́ sí. Àbí, tani kò tìí ní ipa kan nínú tàbí jẹ́ ẹranko nínú eré ìbí Jésù?
Gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́mọbìnrin wúńdíá kan, Màríà. Ó gbé pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ ní Násárétì. A mọ̀ pé Násárétì jẹ́ ọ̀rọ̀ kan fún ìgbàgbé—“Ǹjẹ́ ohun rere kan ha lè jáde wá láti Násárétì.” O fẹ́ẹ̀ jẹ́ ìbéèrè tí kò wuyì ní ìgbà tí a yan ènìyàn tí a kò lè ronú kàn tí ó wá láti ìlú tí kò jẹ́ pàtàkì tí kò sì ní iye. Ṣùgbọ́n èyí sábà máa ń jẹ́ àmì ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú ẹ̀dá ènìyàn—“kí ènìyàn kankan má bàa ṣ'ògo ní iwájú Ọlọ́run.”
Ìgbà mélòó ni a ṣe àṣìṣe àwọn àyànfẹ́, àwọn agbára, àti ọgbọ̀n ènìyàn fún àwọn ti Ọlọ́run? Àwọn ọ̀nà rẹ̀ ga. Èyí túmọ̀ sí pé a kò lè fi ojú inú wò wọ́n tàbí ní òye wọn, kìí ṣe pé wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ohun tí a yóò ṣe, ó ju bẹ́ẹ̀ lọ. Tí ó ga jù lọ, nínú àfiwé yìí, túmọ̀ sí kọjá àrọ́wọ́tọ́ tàbí òye.
Ta ni nínú wa ni yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó kéré jù lọ nínú ibi tí kó ní ọlá jù lọ, ẹni tí a kò mọ iyì rẹ̀ sí, tí yóò sì yan ẹnì kan tí yóò nípa lórí ayé—títí láé? A lọ sí àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tàbí àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó dára jù lọ láti yan ẹni tí ó ní ìlọsíwájú tí ó wú wa l'órí. Olọ́run kò rí béè. Ó máa ń yan ẹni tí a kò rí, àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe agbára tàbí òye wọn ló máa ṣe iṣẹ́ náà. Wọ́n mọ àwọn kù-dìẹ̀ kù-dìẹ̀ wọn, àwọn àṣìṣe, àti ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ní.
Ọlọ́run yan àwọn ẹni tí ó kéré jù, àwọn ẹni tí ó mọ̀ jù lọ nípa àwọn àṣìṣe wọn; àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó máa n di àwọn tí ó mọ́ jù lọ. Nínú Ìjọba rẹ̀, ìgboyà àti ìgbọràn tí ó kéré borí àǹfààní àti afẹ́ ti ayé.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Ìtàn Kérésìmesì wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkéde áńgẹ́lì sí Màríà ó sì parí pẹ̀lú ìbẹ̀wò àwọn amòye. Nínú àwọn àṣàrò wọ̀nyí àti àwọn àmúlò ti ìtàn àkọsílẹ̀ Kérésìmesì èmi yóò tọ́ka sí ìwé Lúùkú púpọ̀, nítorí ìwé tirẹ̀ ni ó kún jùlọ nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìhìnrere.
More