Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò ÌsinmiÀpẹrẹ

Grief Bites: Hope for the Holidays

Ọjọ́ 5 nínú 5

Báwo ni o ṣe lèè ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó ní ìtumọ̀, to kún fún àlàáfíà láì fi ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ṣe?
Nígbàtí a bá wà nínú ọ̀fọ̀, pàápàá jùlọ nígbàtí ẹni tí a fẹ́ràn bá kú tàbí tí a bá pàdánù ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú ẹni tí a fẹràn, a máa dun ni jọjọ láti tẹ̀síwájú láti ṣe àwọn "ohun ọ̀tun mìráàn"...pàápàá l'ákokò ìsinmi. Èyí a máa gba ni l'ásíkò dandan.

Bí ó bá jẹ́ pé ọ ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánú ẹni àyànfẹ́ rẹ bíi oṣù kan tàbí bíi ọdún kan sí ìsinyìí, ó ṣeéṣe kí ọkàn rẹ ṣì gb'ọgbẹ́ kí o má sì mọ̀ bí oó ti ṣe ṣètò tàbí la àkókò ìsinmi yìí kọjá. Àwọn mìráàn kò tilẹ̀ fẹ́ẹ́ ṣe ohunkóhun áńbèlèntorí ki wọ́n máa piyamọ àsìkò pàtàkì fún àkókò isinmi yìí.

Nígbà míràn, ohun tó dára jùlọ tí o lè ṣe ní àsíkò ọ̀fọ̀ ni kí o fún ara rẹ láàyè láti ká gúlútú s'Ọlọ́run l'ọ́rùn kí o sì lo àkókò ìsinmi yìí dááyá pẹ̀lú Rẹ̀, bí o ṣe ń lo àsìkò nínú àdúrà pẹ̀lú Rẹ̀, tí ò ń gbádùn ìfẹ́ Rẹ.

Àwọn míràn lè ní agbára láti gbádùn Kérésìmesì bí wọ́n ti maá ń ṣe tẹ́lẹ̀ nípa ṣíṣe gbogbo ohun afẹ́ àti ohun mánigbàgbé ati àṣa tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe...ẹ̀bùn ńlá lèyí jẹ́!

Ẹlòmíràn lè bá ara rẹ̀ láàrin agbedeméjì....wọ́n fẹ́ láti ṣe àṣà àtyì wá, ṣùgbọ́n wọ́n tún fẹ́ ká'rísọ látàrí pé īgbà náà kò rọrùn fún wọn, wọ́n sì tún ní ọgbẹ́-ọkàn ńlá.

Gbogbo èyí ló yẹ bẹ́ẹ̀ nítorípé ọ̀fọ̀ kìí wá bákannáà. Kò sí "èsì tí kò t'ọ̀nà." Ọlọ́run a màá tọ́ A sì màa darí ọ̀fọ̀ kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ríi pé bí mo bá se f'ojúsun Ọlọ́run sí "ẹni tíi ṣe èrèdí àkókò yìí," bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe lè gbádùn àsìkò Kérésìresì náà tòó. Mo tún ríi pé nígbàtí mo bá mọ̀ọ́mọ̀ f'ara jìn fún ẹlòmíràn l'ákokò ìsinmi yìí tí mo sì ṣe àmúlò àṣà tuntun àti ti àtijọ́, àkókò ìsinmi nàà kò níí jẹ́ èyí tó jẹ́ ẹrù wúwo tó b'ani lérù.

Báwo ni o ṣe máa ń ṣe ohun mánigbàgbé l'ákokò ìsinmi bí o ṣe ń ṣ'àfẹ́rí àwọn ẹni rẹ ọ̀wọ́n tàbí tí ò ń la ìdojúkọ kan kọjá?
Bí bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé kí Ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí kọjá ìrora (bí o ṣe ń gba tí ọ sì ń la ọgbẹ́-ọkàn àti ọ̀fọ̀ náà kọjá) kí Ó sì fi ìtumọ̀ tuntun tàbí àwọn àṣà fún àkókò isinmi lè nira; ṣùgbọ́n ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ran ni lọ́wọ́...kí ó sì wòsàn gidi.

Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé:

Nígbàtí mo wà ní kéreké, mo rántí pé bàbá mi ní kí gbogbo ẹbí wa wọ aṣọ àwọ̀sùn wa kí á baà lè jọ wo iná Kérésì papọ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí mo bí ọmọ t'èmi, gbogbo ìgbà ni a máa ń bu ọlá fún àṣà àrà ọ̀tọ̀ yìí tí a sì màá ń wọ aṣọ àwọ̀sùn wa tí a ó sí jìjọ wo iná Kérésì papọ̀. A ti ń ṣe eléyìí báyìí ó lé ní ògún ọdún.

Àṣà míràn tí mo fẹ́ràn láti ṣe ni kí n se àwọn oúnjẹ Kérésì tí arábìnrin mi fẹràn jù. Màá wá wo ẹni tí ó ní ìbànújẹ́ ọkàn láàrin ẹbí àti ará mi, màá sì wá yà wọ́n lẹ́nu pẹ̀lú oúnjẹ Kérésì tó kààyà yìí. Mo fẹ́ràn láti máa gba'nu níyànjú l'áskokò isinmi kí n sì na ọwọ́ ìtura sí wọn nínú ìbànújẹ́ wọn.

Ọ̀dọ́mọbìnrin kan nínú ẹgbẹ́ aṣọ̀fọ̀ mi, tí ọmọ rẹ̀ obìnrin kú, sọ fún mi pé àkókò ìsinmi maá ń korò fún bíi ọdún mélò kan lẹ́yìn ikú ọmọ rẹ̀. Ọ̀dọ́mọbìnrin yìí tẹ́wọ́gba áńgẹ́lì (ó wá ọmọ tí ó ní ọjọ́ ìbí kannáà pẹ̀lú ọmọ tirẹ̀) láti inú Ẹgbẹ́ Áńgẹ́lì ni agbègbè rẹ̀ yíó sì ra ẹ̀bùn fún ọmọ náà tó wà nínú àìní ní ìrántí ọmọ tirẹ̀..

Kò sí ohun tó burú nínú ki o tán àbẹ́là ìrántí láti bù ọlá fún ẹni rẹ tó sàìsí. Mo ní ọ̀rẹ́ dáada kan tí ó máa ń wá sí àpéjọ ẹgbẹ aṣọ̀fọ̀ mi (òun náà jẹ́ adarí ẹgbẹ́ Grief Bites) tó máa ń tan àbẹ́là ti yóò sì fi àwòrán àwọn òbí rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ àbẹ́là yii. Èyí náà jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkī láii rántí àwọn ẹni ọ̀wọ́n tó ti lo l'ákokò ìsinmi.

Béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run bí Ó ṣe fẹ́ kí o lo àkókò ìsinmi yìí. Ó lè jẹ́ àkókò tí ó tunilára, tó parọ́rọ́ tí ọ ó lò pọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀...ó lè jẹ́ èyí tí oó jẹ́ orísun ìfẹ́ àti kóríyá fún àwọn ẹlòmíràn...ó lè jẹ́ láti s'àjọyọ̀ gẹ́gẹ́ bí o tí maá ń ṣe l'átẹ̀yìnwá...ó lè jẹ́ láti lo àsìkò (kí ọ sì gbádùn pọ̀) pẹ̀lú àwọn ẹni rẹ ọ̀wọ́n...ohun tó dára jù lè jẹ́ kí o rin ìrìn àjò kúrò nínú ìlú...tàbí kí o ṣe gbogbo ohun tí a ti sọ síwájú yìí.
Ọ̀nàkọ́nà tóo bá fẹ́ fi lo àkókò ìsinmi yìí, mo gbàdúrà pé wàá mọ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan bí Ọlọ́run ṣe ń t'ọ́jú rẹ tó. Mo gbàdúrà pé kí ìrètí àti ìfẹ́ Rẹ di mímọ̀ sí ọ ní ìrírí! Mo bèèrè fún ìfẹ́, ìwòsàn àti àlàáfíà fún gbogbo ènìyàn!
Kí àkókò ìsinmi yìí kún fún àwọn ìrántí ìrírí pàtàkì...pàápàá jùlọ ÌRÈTÍ!

Ṣe o tí rí ẹ̀bún TÓ GA JÙLỌ gbà...ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Jésù Kristì?
Wá àsìkò lónìí láti ka Lúúkù 2:1-21 àti Jòhánù 3:16 láti ṣ'àtúpalẹ̀ Ẹ̀bùn tó dára jùlọ tí ẹnikẹ́ni lè fún ọ. Jésù ń dúró pẹ̀lú ọwọ́ méjéèjì yanya láti gbà ọ́ – gẹ́gẹ́ bóo ṣe wà gan-an – àti láti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́. Ohun tó kù ọ́ kù ni kí o bá Ọlọrun ní àjọsọ àtọkànwá nípa pé kí o pe Jésù wá sínú ọkàn rẹ kí o sì bèèrè pé kí Ó sọ ọ́ di titun!

Bí o bá fẹ́ àfikún ìrètí àti ìgbaniníyànjú síi, mo pè ọ́ láti ka àwọn ẹ̀kọ́ wa mìráàn:
•Ọ̀fọ́ Ṣẹ̀: Ṣíṣe Àwárí Ìṣúra Nínú Rògbòdìyàn •Ọ̀fọ́ Ṣẹ̀: Ọ̀nà Tuntun Láti La Ìbànújẹ́ Kọjá •Ọ̀fọ́ Ṣẹ̀: Iyèméjì Yọjú •Kíkọrín Láàrín Ìjì

A tún maá ń gba'ni níyànju l'ójoojúmọ́ l'órí ìkànnì blog àtí ojú ìwé Facebook wa:
•www.griefbites.com
•www.facebook.com/GettingYourBreathBackAfterGrief

O ṣe iyebíye gan-an ni àti pé Ọlọ́run ní àfiyèsí ìbànújẹ́ rẹ! Èmi náà ní àfiyèsí ìbànújẹ́ rẹ pẹ̀lú, mo sì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìfẹ́ wo ọkàn rẹ àti ayé rẹ sàn!
Máa rántí nígbà gbogbo bí Ọlọ́run ṣe ńsìkẹ́ rẹ tó! Ó fẹ́ràn rẹ gan-an gidi dé bii pé Ó ń kọrin Ó sì ń s'àjọyọ̀ l'órí rẹ pẹ̀lú ọkàn tó kún fún ayọ̀! Ìwo ni ayọ̀ ọkàn Rẹ̀! Máṣe gbàgbé bí Ó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ tó kí o sì gbádùn àkókò ìsinmi yìí d'ọ́ba pẹ̀lù Rẹ̀!

"Baba wa Ọ̀run Olóore-ọ̀fẹ́ jùlọ, mo bèèrè pé kí O ṣe iṣẹ́ ńlá nínú ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan lónìí àti ní àwọn ọjọ́ tí ń bọ̀ wá. Nígbàtí ìbànújẹ́ bá g'orí ọkàn wọn, mo bèèrè pé kí O fi ìfẹ́ Rẹ yí wọn ká kí O sì tù wọ́n nínú. Nígbàtí àwọn ọjọ́ bá le koko, mo bèèrè pé kí O bá wọn gbé ẹ̀dùn ọkàn àti ẹrù wúwo wọ̀n. Mo gbàdúrà pé kí O fi ÌRÈTÍ iyebíye Rẹ kún ẹnìkọ̀ọ̀kàn wọn.
Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀, pàápàá jùlọ pẹ̀lú Rẹ. Bí wọn kò bá i tíì gbà Ọ́ l'Ólúwa àti Olùgbàlà wọn, mo gbàdúrà pé kí O tọ́ wọn kí O sì daríi wọn sí ọ̀dọ̀ Olùfúnni-l'ẹ́bùn tó ga jùlọ—Ìwọ tìkaraàrẹ! A fẹ́ràn Rẹ, Olúwa, a sì dúpẹ́ ní ìfojúsọ́nà ohun gbogbo tí O ó ṣe. Ní Orúkọ Jésù ni a gbàdúrà àmín!"

Àyọkà yìí © 2015 làti ọwọ́ Kim Niles/Grief Bites. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà nípamọ́ lábẹ́ òfin. A lòó pẹ̀lú àṣẹ.

Nípa Ìpèsè yìí

Grief Bites: Hope for the Holidays

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Kim Niles, òǹkọ̀wé tó kọ Getting Your Breath Back After Life Knocks It Out of You, fún p'ípèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.griefbites.com