Ọgbẹ́ Ọkàn Dé: Ìrètí L'ásìkò ÌsinmiÀpẹrẹ

Nígbàtí èníyàn bá ń la àdánù nínú ìbájọṣepọ̀ kọjá, bóyá látàrí ikú ẹnití a fẹ́ràn, ìkọ̀sílẹ̀, tàbí rògbòdìyàn nínú ẹbí, àkókò ìsinmi lè sọ ìrètí, ayọ̀ àti adùn rẹ̀ nù pátápátá.
Ọ̀kan lára ìbéèrè tí ó le jùlọ tí ó sì b'ani lọ́kàn jẹ́ jùlọ tí ẹni tí ń ṣ'ọ̀fọ̀ lè d'ojúkọ ni, "Báwo ni màá ṣe gbádùn àsìkò ìsinmi mi tí màá sì tún lè rántí àti bu ọlá fún àwọn àyànfẹ́ ẹni mi tí wọ́n ń lo àsìkò ìsinmi t'iwọn pẹ̀lú Ọlọrun l'ọ́run?"
Ìbéèrè abanilọ́kànjẹ́ mìran tí ẹni (tí ó ń la ikú ẹnití ó fẹ́ràn, ìkọ̀sílẹ̀, tàbí rògbòdìyàn nínú ẹbí k'ọjá) lè ní ni, "Báwo ni màá ṣe lo àsìkò ìsinmi yìí pẹlú gbogbo ìbànújẹ́ ńlá ọkàn mi yìí, àti pé báwo ni màá ṣe lo àsìkò ìsinmi yìí nígbàtí mò ń ṣe àfẹ́rí àwọn ẹni mi tó ti lọ tó yìí?"
Àsìkò ìsinmi a máa jẹ́ àsìkò tó le gan an fún àwọn tí wọ́n wà nínú ìbànújẹ́-ọkàn látàrí ikú ẹnití a fẹ́ràn, ìkọ̀sílẹ̀, tàbí rògbòdìyàn nínú ẹbí tàbí ìyapa.
Àwọn aṣọ̀fọ̀ a máa ṣ'àfẹ́rí ẹni wọn tó ti lọ, àsìkò ìsinmi a máa mú ni rántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí; ṣùgbọ́n ní bàyí rírántí àwọn ìrírí àtẹ̀yìnwá yìí lè mú ọgbẹ́ ọkàn tó burú jáyì lọ́wọ́.
Àwọn ìṣe tó j'ọjú tẹ́lẹ̀ yíó wá di èyí tí ó ń dun ni jọjọ nítorípé ẹni náà tí a fẹ́ràn kò sí l'áyé mọ́ tàbí wọn kò fẹ́ làti bá wa ṣe àjọpín nínú ìrírí yìí mọ́.
Mo ti ṣe àwárí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nìkan ló lè mú ni boríi àkókò tó le àti ọgbẹ́ ọkàn àsìkò ìsinmi... pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀ ojoojúmọ́, ìrànlọ́wọ́, àti ìmúlọ́kànle.
Bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run báyìí pé kí Ó tù ọ́ nínú kí Ó sì wo ọkàn rẹ sàn, àti pé kí o bèèrè pé kí Ó rọ̀'jò ìmúlọ́lànle lé ọ l'órí bí o ti ń la àsìkò ìsinmi yìí kọja...ní ṣísẹ̀-ǹ-tèlé...l'ójoojúmọ́...l'ásìkò l'ásìkò...ìṣẹ̀lẹ̀ kan sí kejì. Ó wà pẹ̀lú rẹ yíó sì gbé ọ sókè pàápàá.
Ní báyìí kíni kí aṣèdárò ṣe pẹ́lú àṣà àtẹ̀hìnwá?
Bí ó bá wú ọ́ làti ṣe àwọn àṣà tí o maá ń ṣe l'átẹ̀yìnwá, ní gbogbo ọ̀nà, ṣe wọ́n...má sì k'ábàmọ̀ pé ò gba ara rẹ láàyè làti y'ayọ̀. Àwọn àyànfẹ́ rẹ gbádùn wọ́n sì fẹ́ràn láti máa ríi pé o kún fún ayọ̀ nígbà ayé wọn. Yíó sì tún wù wọn láti ríi pé o kún fún ayọ̀ lẹ́ẹ̀kansii, kódà bí o ṣe ń la àsìkò ìbànújẹ́ rẹ kọjá.
Bí o kò bá fẹ́ láti ṣe àwọn àṣà àtẹ̀yìnwá tí ẹ màa ń ṣe, bu ọlá fún ìbànújẹ́ rẹ nípa gbígba ara rẹ láàyè làti kẹ́dùn bí ọ ṣe yẹ kí o kẹ́dùn. Má k'àbámọ̀ pé ó wù ọ́ láti ní àsìkò ìsinmi tó gbáfẹ́ tó sì parọ́rọ́.
Ọ̀nà méjèèjì ló tọ́ làti d'árò.
Má jẹ̀ kí ohunkóhun tì ọ́ l'ọ́pọnpọ̀n-ọ́n làti k'ẹ́dun tàbí ṣèd'árò bákan tàbí tì ọ́ láti ṣe ohun tí kò l'ákàsí ipò tí o wà nínú ìdárò rẹ.
Àwọn aṣèdárò míràn lè fẹ́ làti ṣe àwọn àṣà àtẹ̀yìnwá tí wọ́n gbádún láti máa ṣe pẹ̀lù àwọn àyànfẹ́ wọn bíi ọ̀nà láti máa rántí wọn àti ọ̀nà láti bu ọlá fún wọn, nígbàtí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ èyí tí ó dun ni jọjọ fún àwọn aṣèdárò míràn l'ásìkò yẹn.
Bá àwọn àyànfẹ́ ẹni rẹ tó sì wà láàyè sọ̀rọ̀ kí o sì sí ọkàn rẹ payá fún wọn nípa ṣíṣe àlàyé b'ó ti n ṣe ọ́. Bèèré fún ìfẹ́ àti ìgbéninígbọ̀nwọ́ wọn l'ásìkò ìsinmi yìí.
Fi àwọn onígbọ̀nwọ́ rẹpẹtẹ yí ara rẹ kà!
Bí ilé-ìjọsìn kan bá sún mọ́ ọ tí wọ́n ní ẹgbẹ́ onígbọ̀nwọ́ fún àwọn aṣèdárò, bíi GriefShare tàbí Grief Bites, mo rọ̀ ọ́ tọkàntọkàn làti d'ara pọ̀ mọ́ wọn.
Àkókò wà fún ohun gbogbo, àti fún wíwá ìgbaniníyànjú àti ìgbọ̀nwọ́, Ọlọ́run sì jẹ́ olóòtọ́ làti mú ọ la gbogbo ìgbà ayé rẹ kọjá. Bu ọlá fún Ọlọ́run àti ìdárò rẹ.
Gba Ọlọ́run láàyè làti tọ́ àti làti darí arò àti ọgbẹ́-ọkàn rẹ, kí o sì bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ fún ọ̀nà tó tọ́ jù láti ṣe àṣà àtẹ̀yìnwá ati làti lo igba àyé rẹ yìí.
Láàrín bíi ọjọ́ méjì, màá máa ṣe ìṣítí lórí àwọn ọ̀nà tí a lè gbà lo àsìkò ìsinmi, àti bí a ó ṣe ní ìfọ̀kànbalẹ̀ kí a sì ṣe àgbékalẹ̀ ìrírí tí yíó ní ìtumọ̀ l'ásìkò ìsinmi yìí.
Pe Ọlọ́run, ní báyìí, láti jẹ́ Ọ̀rẹ́ tó ṣe iyebíye l'ákòkò ìsinmi yìí àti ní àwọn ìgbà tó tẹ̀lée.
Àdúrà:
"Baba wa Ọ̀run Olóore-ọ̀fẹ́ jùlọ, mo fi ọpẹ́ fún Ọ nítorípé mi ò ní nìkàn dá lo àkókò ìsinmi yìí. Mo dúpẹ́ làti odò ikùn mi wá pé O wà pèlú mi nígbà gbogbo, O fẹ́ràn mi, O kò sì fi ìgbà kankan fi mí sílẹ̀ tàbí kọ̀ mí sílẹ̀. Abba Bàbá, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ ní gbogbo ọjọ́ bí mo ti ń la ìbìnújẹ́ àti ọgbẹ́-ọkàn mi kọjá. Ràn mí lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ṣe ìrántí àwọn ẹni mi tó ti lọ, láti fi gbogbo ohun tí ó kó ọkàn mi ní papá mọ́ra sílẹ̀, kí n sì rí oore àti ìbùkún Rẹ kedere láàrin ìjì tí mò ń d'ojúkọ l'áyé.
Mo féràn Rẹ Olúwa, mo sì yin Orúkọ mímọ Rẹ. Ní Orúkọ Jésù ni mo gbàdúrà, Àmín."
Àyọkà yìí © 2015 làti ọwọ́ Kim Niles/Grief Bites. Gbogbo ẹ̀tọ́ wà nípamọ́ lábẹ́ òfin. A lòó pẹ̀lú àṣẹ.

Nípa Ìpèsè yìí

Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkókò ìsinmi jẹ́ àkókò ayọ̀ ńlá...ṣùgbón kíni yío ṣẹlẹ̀ nígbàtí àkókò ìsinmi bá sọ adùn rẹ̀ nù tí ó bá sì di àkókò ìpèníjà látàrí ìbànújẹ́ tàbí àdánù ńlà? Ètò ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí yíó ran àwọn tí ó ń la ìbànújẹ́ kọjá láti ṣàwárí ìtùnù àti ìrètí l'ákòkò ìsinmi, àti láti ṣ'àgbékalẹ̀ àkókò ìsinmi tó n'ítumọ̀ làì fi ti ìbànújẹ́ ọkàn ṣe.
More
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Kim Niles, òǹkọ̀wé tó kọ Getting Your Breath Back After Life Knocks It Out of You, fún p'ípèsè ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: www.griefbites.com