Fífetí sì Ọlọ́runÀpẹrẹ

Listening To God

Ọjọ́ 5 nínú 7

Àwọn Ààmì Àìsan Etí-Dídi

Ádámù àti Ééfà mọ Olúwa dáradára! Àwọn ẹbí ìpín tíó tẹ̀lé wọn mọ Olúwa pẹ̀lú, bí kò tilẹ̀ tó ti àwọn òbí wọn. Díẹ̀-díẹ̀, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ọ̀pọ̀ ènìyàn fàsẹ́yìn nínú ìdúpẹ́ àti ìmore sí Olúwa gẹ́gẹ́ bíi orísun wọn. Ẹ̀ṣẹ̀ wá pọ̀si.

.

Púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀sẹ̀ kékèké jẹ́ àmì àìsàn gbòǹgbò-ẹ̀sẹ̀ tó ti fẹsẹ̀ múlẹ̀: ẹ̀sẹ̀ kíkọ etí ikùn sì òtítọ́ Olúwa, àti títẹ́ etí sílè láti gbọ́ irọ́. Nígbà tí a bá kùnọ̀ láti rí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olùpèsè gbogbo ohun tódára, a ò lè ríran dáradára mọ́. A ò lè ronú bíi ọlọ́gbọ́n mọ́. A ó kọ̀ láti tẹ́tí sì òtítọ́. Ìwé Róòmù orí kìíní fi òtítọ́ yìí hàn gbàngbà-gbangba.

Gbólóhùn ìrọra kan nìyí: kíkọ̀ láti tẹ́tí sì òtítọ́ túmọ̀ sí kíkọ Oluwa. Nísinsìnyí, gẹ́gẹ́bí Krìstẹ́nì, a gba ọ̀rọ̀ Olúwa bíi òtítọ́. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ rí dájú wípé gbogbo òwú etíi wa làá ń yọ kúrò nípa ìdámọ̀ àti ìkọ̀sílẹ̀ irọ́-bíi-òtítọ́, àti láti máa tẹ́tí lélẹ̀ sí ohùn Olúwa.

Ohun tó fà àròjinlẹ̀ ni láti mọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó kọ òtítọ́ a máa wọ́ àwọn mìíràn lọ sí inú ẹ̀tànjẹ wọn, bí ati kọ́ níbi tí a kà nínú ìwée Jẹ́nẹ́sísì. Ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí. Tani ó séése láti jẹ̀yà bí ó kòbá tẹ́tí sí ohùn Olúwa? Ṣé ọkọ/aya? Ọ̀rẹ́ rẹ? Ọ̀gá rẹ? Àwọn ọmọ rẹ? Kódà bóyá àlejò kan tí Olúwa fẹ́ rán ọ sí?

Mo lérò pé àkókò yìí dára fún mi láti kó gègé mi ní'jánu, kí ìwọ báa lè tẹ́tí lélẹ̀ nínú àdúrà.

Bèrè lọwọ Baba: Ǹjẹ́ Iwọ́ lè fi hàn mí, gbogbo irọ́ tí mo ti gbàgbọ́?

Orin ìjọsìn tí òní: “Kòsí Orúkọ Míràn” tí a tẹnu ẹgbẹ́ Hiilsong Worship kọ

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Listening To God

Amy Groeschel ti kọ ètò bíbélì yìí ní ìrètí pé yóò di ìtẹ́wọ́gbà bíi wípé ó wá tààrà láti ọkàn Ọlọ́run olùfẹ́ wa sí ọkàn rẹ. Àdúrà Òun tìkálára ni wípé yóò kó̩ ọ láti yàgò fún ohùn tí ń tako ni àti láti tani jí sí ìfiyè sí ohùn rẹ̀.

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọ Life.Church fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí www.life.church