Fífetí sì Ọlọ́runÀpẹrẹ

Ẹ̀tànjẹ Ìfẹ́kùfẹ́
Orísun ẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn irọ́ wọ̀nyí: Olúwa kò dára, kò séé gbẹ́kẹ̀lé, Ó ti kọ̀wá sílẹ̀. Dájúdájú ẹ̀tànjẹ yìí sì wà títí dòní. Bíi wípé èyí kò tíì burú tó, bíi Eéfà, àwọn ìlépa wa a máa lọ l'ẹgbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn irọ́ wọ̀nyí! Sátánì nílò gbogbo ẹ̀tànjẹ yìí fún ìgbìyànjú láti mú ìyapa wá láàrín àwa àti Olúwa.
Eéfà rí èso àjàrà náà, ó sì gbàárò wípé ó dáa lójú, ó sì dùńwò. A túnbọ̀ tàán jẹ́ pẹ̀lú ìlérí ẹ̀bùn ìṣíni-níyè, ìmọ̀, àti tó bá ṣeé ṣe - àní kún agbára. Ó lérò pé òhun yóò dabi Olúwa. Ṣùgbọ́n, ẹ̀tànjẹ ńlá gbáà ni!
Ìwọ wáá ńkọ́? Ẹ̀melò ni ìfẹ́kúùfẹ́ ojú àti ọgbọ́n kúkúrú tí ṣá ọ balẹ̀? Kìí se ìfẹ́ẹ̀ mi láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá ọ pẹ̀lú ìbéèrè yìí, bí kò ṣe láti ta ọ́ jí nítorí, o kò nílò láti dúró dìgbà tí ǹkan bá bàjẹ́ tan, ọ̀rẹ́!
Gbígbé ayé wa ní ìbásopọ̀ pẹ̀lú ohùn Olúwa túmọ̀ sí pé à ń rìn ní ìlànà rẹ̀ láti bu'ọ́la fún. Fi ògo fún, ọpẹ́, àti ìyìn nítorí gbogbo ìgbà tí ó ń wà pẹ̀lú rẹ! Ìbásopò mímó yìí túmọ̀ sí wípé a gbẹ́kẹ̀lé Olúwa ni gbogbo ọ̀nà, àti wípé àwa yóò sé etí àti ojú wá sí gbogbo ẹ̀tànjẹ tí ò lè fẹ́ múlẹ̀ nínú ọkàn wa.
Ayé yìí kìí ṣe ìpín mi, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe tìrẹ pẹ̀lú! Ọrùn àti ayé títún ń dúró de àwọn tío ń fi ìrọ́jú tẹ̀ síwájú láti máa gba Olùgbàlà wọn gbọ́. A kò nílò láti máa tẹ̀lé àwọn àṣà àti ìṣe tí kọjá lọ. A kò nílò láti máa fòyà wípé àwọn "ohun dídára" yóò fò wá ru, nítorí a mọ̀ dájú wípé èrè ńlá tí kìí díbàjẹ́ ń dúró dè wá. Àti wípé, a mọ̀ ní tòótọ́ wípé Olúwa nìkan ni Ohun tí ó dára! Ó jẹ́ Ohun gbogbo nínú Ohun gbogbo fún wa, Ẹni tí ó tó wa, Aláṣèpe wa!
Béèrè lọ́wọ́ Baba: Ǹjẹ́ ohun kan wáà tí mo nílò láti ṣe tàbí mọ̀ fún ìfẹ́ ọkàn mi láti jẹ́ Tìrẹ ní gbogbo ìgbà?
Orin ìjọsìn tí òní: "Ẹ palẹ̀ pẹpẹ ètò mọ́" tí a tẹnu Jimmy Needham kọ
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Amy Groeschel ti kọ ètò bíbélì yìí ní ìrètí pé yóò di ìtẹ́wọ́gbà bíi wípé ó wá tààrà láti ọkàn Ọlọ́run olùfẹ́ wa sí ọkàn rẹ. Àdúrà Òun tìkálára ni wípé yóò kó̩ ọ láti yàgò fún ohùn tí ń tako ni àti láti tani jí sí ìfiyè sí ohùn rẹ̀.
More