Kíni Ìdí Àjíǹde?Àpẹrẹ

Why Easter?

Ọjọ́ 1 nínú 5

Kíni ìdí tí a ṣe nílò Jésù?

A dá ìwọ àti èmi láti gbé nínú ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run. Tí a kò bá tíì ní ìbátan yìí, yíò dàbí wípé n ǹkankan sọnù nínú ayé wa. Nítorí èyí, a má ń sábà sàkíyèsí àlàfo yìí. Ọ̀kan nínú àwọn akọrin òde òní ṣàlàyé rẹ̀, ó ní: 'Mo ní àlàfo kan tí ó jinlẹ̀ nínú mi.'

Arábìnrin kan kọ ìwé ránsẹ́ sí mi, ó kọ nípa àlàfo tí ó jìn. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan náà sọ nípa 'ìṣù kan tí ó sọnù nínú ẹ̀mí rẹ.'

Àwọn ènìyàn a máa gbìyànjú láti fi n ǹkan dí àlàfo yìí ní orísìrísi ọ̀nà. Àwọn kan gbìyànjú lati fi owó dí àlàfo yìí, ṣùgbọ́n èyí kò fún wọn ní ìtẹ́lọ́rùn. Aristotle Onassis, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní owó jù ní àgbáyé, sọ ní ìgbẹ̀yìn ayé rẹ: 'Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kì í fìgbà gbogbo pọ̀ sí ohun tí ènìyàn nílò nínú ìgbésí ayé

Àwọn míràn gbìyànjú láti lo àwọn ògùn olóró tàbí otí àmupára tàbí ìbálòpọ̀ panságà. Ọ̀dọ́mọbìnrin kán sọ fún mi, ó ní, ' Gbogbo àwọn nǹkan yìí á fún ènìyàn ní ìdùnnú ìgbà díẹ̀ ṣùgbọ́n láìpẹ́ ojú a wá lẹ̀ yíò sì padà sí ìmọ̀lára kòrọ̀ fọ yìí.' Áwọn míràn a sì tún gbìyànjú láti ṣiṣẹ́ àsekára, tàbí orin kíkọ, ṣeré ìdárayá tàbí kí wọ́n máa wá àṣeyọrí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kìí ṣe pé àwọn ìgbìyànjú yìí kò dára ní ti ara wọn, ṣùgbọ́n wọn ò le dípò ìpòǹgbe tí ó wà nínú àwa ọmọ ènìyàn.

Kódà ìbátan tí ó súnmọ́ jù láàrin àwa ọmọnìyàn, wọ́n dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n wọn kò le dípò 'àlàfo tí ó jinlẹ̀ nínú wa'. Kò sí ohun tí ó lè dí àlàfo yìí àfi ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ìdí tí a ṣe dá wa.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ́ nínú Májẹ̀mú Títún, ìdí àlàfo yìí ni wípé ọkùnrin àti obìnrin ti kọ ẹ̀yìn wọn sí Ọlọ́run.

Jesu wí fún wọn pé, “Èmi ni oúnjẹ ìyè'(John 6:35 Byo). Òhun nìkan ni ó lè tẹ́ wa lọ́rùn nítorí wípé òhun ni ó ń jẹ́ kí ìbátan wa padà pẹ̀lú Ọlọ́run ṣeéṣe.

a) Ó ń tán ìpòǹgbe wa fún ìtumọ̀ àti ète Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé

Nínú ìbátan pẹ̀lú asẹ̀dá wà nìkan ni a lè ri ìtumò tòótọ́ àti ète Ọlọ́run fún ayé wa.

b) Ó ń tán ìpòǹgbe wa fún ìyè tí ó kọjá ikú

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni kò fẹ́ kú. À ńfẹ́ láti yè kọjá ikú. Nínú Jésù Krístì nìkan ni a rí ìyè àìnípẹ̀kun.

c) Ó ń tán ìpòǹgbe wa fún ìdáríjì

Tí a bá jẹ́ olóòtítọ́, gbogbo wa ni á gbà wípé à ńṣe àwọn nǹkan tí a mọ̀ wípé kò tọ́ láti ṣe. Nípa ikú Jésù lórí igi àgbélèbú, Jésù jẹ́ kí ó ṣeéṣe fún wa láti rí ìdáríjì kí á sì mú wa padà bọ̀ sínú ìbátan pẹ̀lú Ọlọ́run

Ìwé mímọ́

Nípa Ìpèsè yìí

Why Easter?

Kíni ohun tó ṣe pàtàkì gan nípa àkókò Àjíǹde? Kíló ṣe tí gbogbo ojú fi wà ara ẹnìkan tí a bí ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn? Kílódé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fi n ní ìtara nítorí Jésù? Kíni ìdí tí a fi ní lò Rẹ̀? Kílódé tó fi wá? Kílódé tó fi kú? Kíni ìdí tí ó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni gbèrò láti wádìí? Nínú ètò ìlànà ọlọ́jọ́ 5, Nicky Gumbel pín àwọn ìdáhùn tó múná d'óko sí àwọn ìbéèrè náà.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Alpha àti Nicky Gumbel tí wọ́n pèsè ètò ìlànà yí. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ lo sí: https://alpha.org/