Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ

How To Study The Bible (Foundations)

Ọjọ́ 3 nínú 5

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ó Múná D'óko Nílò Àtìlẹyìn Àwọn Irinṣẹ́


Bí irinṣẹ́ tí ènìyàn ń lò bá ṣe dára tó ni iṣẹ́ rẹ̀ ṣe máa dára sí. – Emmert Wolf 


Ọ̀kan lára àwọn ǹkan tí mo fẹ́ràn láti máa ṣe ní ọjọ́ tí ń kò bá lọ sí ibi-iṣẹ́ ni wíwo àwọn ètò ìdáná lórí mọ́hùn-máwòrán pẹ̀lú ife àgbo t'ó lọ́ wọ́rọ́wọ́. Ǹkan ìwúrí ni láti máa wo alásè àgbà ní ibi tí ó ti ń dáná. Gbogbo ǹkan tí wọ́n bá ṣe ló ní ìwúlò tirẹ̀ láti orí ìsebẹ̀ tí wọ́n ń lò, lọ sí orí bí apẹ ìdáná wọn ti gbóná sí, títí dé orí irúfẹ́ abọ́ tí wọ́n ń fi bu oúnjẹ náà. 

Bí o bá bèrè lọ́wọ́ àwọn alásè gbajúgbajà yìí nípa ǹkan tí ó ṣe pàtàkì jù lọ nípa iná dídá, ìdáhùn kan náà ni púpọ̀ nínú wọn máa fún ọ: èlò. Bí èlò ọ̀hún bá ṣe jẹ́ ọ̀ńwọ́n tàbí titun sí, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ tí ó máa tẹ̀yin rẹ̀ yọ yóò ti jẹ́ àgbàyanu.

Fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn èlò wa ni àwọn irinṣẹ́ tí a máa ń lò láti ní òye Ìwé Mímọ́ síi. Bí a bá lo irinṣẹ́ rere, a máa ní òye tí ó múná dóko nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, a ó sì kọ́ bí a ṣe lè ṣe àmúlò àwọn òtítọ́ méle-gbàgbé yìí tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́ tí a bá lo àwọn “èlò” tí ó kù díẹ̀ káàtó tàbí tí ó mẹ́hẹ, òye wa nípa Bíbélì náà máa mẹ́hẹ àti wípé ó tilẹ̀ lè mú wa lọ sí ipa tí ó léwu.

2 Tímótì rọ̀ wá láti di òṣìṣẹ́ tí ó dáńtọ́ nípa ṣíṣe àmúlò “ọ̀rọ̀ òtítọ́” nì ọ̀nà tí ó “yẹ.” Ọ̀nà tí ó dára jù lọ tí mo mọ̀ láti gbé èyí gbà ni: 

  1. Ṣe àwárí àwọn irinṣẹ́ tí ó wà ní àrọ́wọ́tó rẹ láti lè ràn ọ lọ́wọ́ fún òye Bíbélì.
  2. Gbàdúrà kí Ọlọ́run darí rẹ sí ọ̀dọ̀ olùtọ́ni rere tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àmúlò àwọn irinṣẹ́ yìí. 

Ní báyìí, ó rọrùn láti ní ìpòrúru ọkàn pẹ̀lú bí ogunlọ́gọ̀ irinṣẹ́ ṣe pọ̀ lóde fún òye Bíbélì. Àlaye gígùn, ìwé ìtumọ̀, ìwé atọ́ka, onírúurú máàpù, áàpù akọ́nilédè, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni ó wà. Àmọ́ irinṣẹ́ àkọ́kọ́ tí mo ma ń sábà gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mi ní ìmọ̀ràn láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ni: ìtumọ̀ Bíbélì tí ó dára. 

Ó tún jẹ́ ǹkan ìdùnnú wípé àwọn irinṣẹ́ bíi ohun èlò Bíbélì láti ọwọ́ YouVersion múu rọrùn láti ka onírúurú iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì. Ibi tí mo lè gbà ọ́ ní ìmọ̀ràn láti bẹ̀rẹ̀ nìyí. 

Ìṣúra ń dúró nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run de àwọn tí ó ṣe tán láti lépa rẹ̀. 


Ìmọ̀ràn-ńlá: Ṣé o fẹ́ mú ẹ̀kọ́ Bíbélì rẹ lọ sí ipele tí ó kàn, àmọ́ o kò mọ pàtó ibi tí ìwọ á ti bẹ̀rẹ̀? Yan àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì tí o fẹ́ràn jù lọ kí o sì kọ ìtumọ̀ márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ẹsẹ̀ yíi sí inú ìwé kan. Kí ni àwọn ìyàtọ̀/àfarajọ tí o ṣe àkíyèsí rẹ̀? Ìfọkànsí rẹ gẹ́gẹ́ bíi olùkà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn irinṣẹ́ tí ó dára jù lọ tí o lè bá pàdé. 

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

How To Study The Bible (Foundations)

Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ Faithspring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com