Bí A Ṣe Lè Ka Bíbélì (Àwọn Ìpìlẹ̀)Àpẹrẹ

How To Study The Bible (Foundations)

Ọjọ́ 2 nínú 5

Àṣà ni Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí ó Làmìlaka


Àwa yíò di ohun tí à ń ṣe léraléra – Sean Covey


Bí a fẹ́ bí a kọ̀ ìgbé ayé wa dá lórí àwọn ìṣesí wa. Oúnjẹ tí a ń jẹ, ìhà tí a kọ sí wàhálà, bóyá a kò gbà agogo ìtanijí láàyè tàbí a gbà–gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó ń sọ ohun tí ìṣesí tí a gbà láàyè nínú ayé wa jẹ́.

Òǹkọ̀wé Charles Duhigg kọ̀wé pé ó súnmọ́ ìdá 45 gbogbo ohun tí a ń ṣe ní ọjọ́ kan, àti ní ojoojúmọ́, ní ó jẹ́ àṣà wá. Tí o bá ní ìwà rere, eléyìí jẹ́ ìgbìyànjú tí ó dára. Ṣùgbọ́n tí àwọn ìṣesí rẹ kò bá jẹ́ ohun tí o fẹ́ kí wọ́n jẹ́, èyí túmọ̀ sí pé ìdajì àwọn ìpinnu tí o ní ànfàní láti ṣe ni a ti yàn fún ọ (wọn kò sì yàn wọ́n dáradára).

Mo ń sọ èyí fún ọ nítorí pé mo fẹ́ kí o di èyí mú bí ó ṣe ṣe pàtàkì sì láti lọ sínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní òòre-kóòrè.

Kini ìdí tí àwọn òmìrán ìgbàgbọ́ tí a rí nínú Ìwé Mímọ́ ṣe wẹ̀ tí wọ́n sì yán kọ̀ǹkọ̀n? Nítorí pé kò sí ìdúnádúrà nípa àkókò lílò pẹ̀lú Ọlọ́run àti nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Pẹ̀lú gbogbo àwọn àṣìṣe tí Ọba Dáfídì ṣe, ó ń padà wá sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó tún ìgbésí ayé rẹ ṣe gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ó sọ, ó sì ní ipá l'órí ìtàn Israeli nítorí rẹ̀.

Pọ́ọ̀lù dàgbà di Farisí òní-tárá tí Ìwé Mímọ́ ń hó lórí rẹ̀. Ní kété tí Jésù mú àyípadà bá ìgbésí ayé rẹ̀, ó súnmọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé ọ̀tun, ó sì mú ìdí tí ó fi wá sí ayé ṣẹ́ nítorí bẹ́ẹ̀.

Tí ẹnikẹ́ni bá yege nínú kíka Bíbélì ni ojoojúmọ́ bí àṣà, Jésù ni ẹni náà. Síbẹ̀síbẹ̀ ní ìgbàkúùgbà ni Ó máà ń yọ́ lọ ka Bíbélì àti láti gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́. Ó ní òye, Ó sàn ju ẹnikẹ́ni nínú wa lọ, báwo ni ènìyàn bí àwa ṣe nílò láti jẹ́ kí àwọn ìpàdé wá pẹ̀lú Ọlọ́run jinlẹ̀ tó.


Fún ìtọ́ni: Ṣé ò ń jìjàkadì láti ka Bíbélì rẹ nígbà gbogbo bí? Fi sílẹ́ ní ṣíṣí kí o sì gbé sí àbáwọlé ìyára tàbí ilé oúnjẹ. Nípa ṣíṣe èyí, bí o ṣe ń kọjá lọ kọjá bọ̀ láti ṣe iṣẹ́ òòjọ́ rẹ, ìwọ yíò ka ẹsẹ Bíbélì kan ó kéré jù. Àfojúsùn láti lè ní ìpìlẹ̀ àṣà Bíbélì kíkà ní láti jẹ́ kí ó rọrùn (ẹ́sẹ́ kan), àti l'áti máa fi ojú rí i (ó ti wà ní ṣíṣí, ó sì wà ní ọ̀nà rẹ).

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

How To Study The Bible (Foundations)

Ó rọrùn láti rẹ̀wẹ̀sì, láti rò pé a kò múra tó, tàbí pé a kò ní ìtọ́sọ́nà ní ìgbà tí ó bá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èrò mi ni láti mú ìlànà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rọrùn fún ọ ní àwọn ọ̀nà díẹ̀ nípa kíkọ́ ọ ní mẹ́ta nínú àwọn ìlànà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ láti ṣe àṣeyọrí nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. D'ara pọ̀ mọ́ ètò yìí kí o ṣe àwárí bí o ṣe lè ka Bíbélì, kìí ṣe fún àlàyé nìkan, ṣùgbọ́n fún ìyípadà ìgbésí ayé lónìí!

More

A fẹ́ dúpẹ́ ní ọwọ́ Faithspring fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé sí iwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.fromhispresence.com