Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Iṣẹgun Àjálù
Nígbàtí onkọ̀we ba jóko láti kọ àràmàdà, o ti mọ̀ síwájú bi ìwé náà yóò ṣe parí. Ó mọ àwọn ìforígbárí tí àwọn òṣeré pàtàkì inú rẹ̀ yóò dojú kọ àti bí wọ́n ṣe máa borí.
Bákan náà ni pẹlú Ọlọ́run. O n kọ ìtàn rẹ́, Ó sì ti mọ òpin rẹ̀. Nígbà mìíràn, a ó fẹ kígbe, "Kíni yóò ṣẹlẹ̀?" A fẹ láti wo ojú-ìwé tí o kẹhìn. Láìsí gbogbo ìtàn náà, òógún ìjàkadì ní fún wa láti gbẹkẹlé wípé ìpinnu Ọlọ́run lórí ìṣòro yìí tó láti fi ará rọ́ ẹ̀dùn to mú lọwọ.
Jóòbù jẹ́ àpẹẹrẹ pípé ti enìkán tí ọkàn rẹ̀ yíò ti dàrú lórí kínní ìpinnu Ọlọ́run fun nínú ìjìyà rẹ. Ó ké pe Ọlọ́run nínú ìbànújẹ́ rẹ̀, ó sì sún mọ́ àìnírètí ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run rán Jóòbù létí wípé àwọn ìlànà àti iṣisẹ Rẹ̀ máa ń borí nígbà gbogbo. Bí Ọlọ́run ò tílẹ sọ fún Joobu ìdí tí o fi n jìya, Ó ṣèlérí fún Jóòbù pé òun ṣì wà nípò àṣẹ.
A le má gbọ ìtàn nlá tí bí ìjìyà wá ṣe nṣiṣẹ́ wọ inú ìlànà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí a fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa mímọ̀ pé Ọlọ́run máa ń ní èto nígbà gbogbo fún ohùn tí a ń là kọjá.
A lè fi sùúrù dúró de ètò Ọlọ́run nígbà tí a bá mọ̀ wípé kò ní kùnà láé. Ìjìyà wá jẹ́ apá kékeré kan nínú ìtàn nlá ti ìfẹ Ọlọ́run sí àgbayé.
Àdúrà: Ọlọ́run ọ̀wọ́n, nígbà míràn ó máa ń ṣòro fún mi láti ní ìgbàgbọ́ nígbà tí n kò bá lè rí èto nínú ìyà mi. Fún mi ní sùúrù kí O sì ràn mi lọwọ́ láti gbẹkẹlé wípe nígbà gbogbo ní O wà ni ìṣàkóso. O ṣeun fún ètò pípé Rẹ fún àgbayé. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More