Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Ẹ̀bùn Àánú
Tí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀tọ́ láti máa ní ìdùnnú, Hellen Keller ni. Ó jẹ́ afọ́jú àti adití, àti àwọn àìlera rẹ̀ jẹ́ kí ó máa ní ànfàní rárà láti rí ìrírí ayé ní ọ̀nà tí ọpọlọpọ wá ṣe rẹ. Gbogbo ènìyàn tí ó wà ní àyíká rẹ̀ ní àwọn agbára tí kò ní. Ṣùgbọ́n ó ní ìpinnu, àti nǹkan tí ó níyelórí jùlọ - àánú.
“Ní ìgbàgbó, nígbà tí inú rẹ kò dùn jùlọ, gbà pé ohun kan wà fún ọ láti ṣe ní àgbáyé,” ó sọ pé. "Níwọ̀n ìgbà tí o bá lè mú adùn sí inú ìrora ẹlòmíràn, ìgbésí ayé kìí ṣe asán."
Nígbà tí Helen ti dàgbà, ó máa ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò rẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìwòsàn fún àwọn ọmọ ogun tí ogun ti fọ́ wọn lójú tàbí tí wọ́n ti di etí. Ó lọ láti fi ìrètí hàn wọ́n pé wọ́n le gbé ìgbésí ayé eléso lẹ́yìn àwọn ìpalára wọn. Ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe sọ ìrètí nù fún ọjọ́ ọ̀la wọn. Àwọn àìlera rẹ̀ fún u ní àyè láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tí ó ní dojúkọ tí ó lágbára.
Ronú nípa rẹ̀ láti ìrísí Helen. Ó lè sọ pé, “ adití àti afọ́jú ni mí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sì kàn jẹ́ afọ́jú. Mọ ní ìṣòro tí ó ju ti wọn lọ. Ó le yàn láti banújẹ́, kí ó bínú tàbí kó dójú lórí àwọn ìṣòro tí rẹ. Ṣùgbọ́n dípò, ó yàn láti lo àwọn ipò rẹ̀ láti ṣe àánú fún àwọn tí ó wà ní àyíká rẹ̀.
Láti fi “ẹ̀tọ́” tiwa sílẹ̀ láti wá nínú ìrora wa àti yíyan láti ṣe àánú fún àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ohun líle. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá jìyà, a ní agbára tí ó ga síi láti bá àwọn ẹlòmíràn kẹ́dùn.
kàkà kí á ma fi ìṣòro wé ran wọn tàbí kí á ma ṣé ìdájọ́ ẹni tí ó ní ìṣòro jùlọ, a le yàn láti jẹ́ oní bùkún.
Àdúrà: Olúwa mi, o ṣé fún ẹ̀bùn àánú. Mo mọ̀ pé nígbà tí mo bá la ìjì líle nínú ìgbésí ayé mi, mo ní agbára tí ó pọ̀ sí i láti ṣàánú àwọn ẹlòmíràn. Rán mì lọ́wọ́ láti lo agbára yẹn bùkún àwọn tí ó wa ní àyíká mi. Àmín.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.
More