Ṣíṣe Àwàrí Òtítọ́ Ọlọ́run Nínú Ìjì AyéÀpẹrẹ

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Ọjọ́ 3 nínú 10

Èrèdí Àwọn Ìdánwò

Kí wọ́n tó dojú kọ ìdánwò pàtàkì, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ àwọn Krìstẹ́ní máa ń gbàgbọ́ pé òye ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Rómù 5: 3-4 yé àwọn dáradára àti pé àwọn lè mú un lò nínú ayé àwọn tí ìgbà ìṣòro bá dé. Lẹ́hìn náa, gbogbo nnkan yí padà. Bóyá wọ́n pàdánù ẹnìkan tí wọ́n fẹ́ràn ni, bóyá ìdààmú dé bá ìgbéyàwó wọn tàbí wọ́n gba ìpè fóònù kan láti ọ̀dọ̀ dókítà pé "Ẹ ní jẹjẹrẹ."

Ní irú àwọn àkókò báyìí ni ó máa ń yé wa bí a ti ṣe aláìlágbára tó ... àkókò yìí lè jẹ́ ìgbà tí nnkan kan kò yé wa mọ́. Ṣùgbọ́n ní àwọn àkókò yìí, a lè yan ohun tí a fẹ́. A lè kọ ẹ̀hìn wa sí Ìgbàgbọ́ Nínú Krístì, kí á sá fún ohun tí ó jẹ́ òtítọ́, tàbí kí á gbà pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni nnkan tí ó dé bá wa.

A ní láti ní àforítì. A ní láti gbàgbọ́ pé Ọlọ́run--tí ó mọ iye irun orí wa--bìkítà tó láti tọ́jú wa, ohunkóhun tí ó lè wù kí ó lè dé. A sì ní láti máa rán ara wa létí ìyẹn ní àràárọ̀.

Ní ojoojúmọ́ tí à ń farada ìdánwò à ń dàgbà nínú ipa wa láti ṣe àforítì ní àkókò ìdààmú. Ṣíṣe àforítì jẹ́ ohun tí Ìwé Mímọ́ pa ní àṣẹ pé kí á máa ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀. Nítorí náà dídàgbà nínú àforítì kìí ṣe nnkan tí a gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ mú!

Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé àforítì tí ó ti ibi ìnira dìde wá máa ń jẹ́ kí á ní ìwà. Bí a ṣe ń d'ojú kọ àwọn ìjìyà wa tí a sì ń borí wọn, à ń di alágbára síi. A ó bẹ̀rẹ̀ sí dàgbà nínú ìgbàgbọ́ tí ó rinlẹ̀, á sì rán wa létí agbára tiwa. Àwọn ènìyàn tí wọ́n tí fi ara da ìjìyà kìí yára fi ara mọ́ èróńgbà ti àwọn ẹlomíràn. Wọ́n lè fi ara da ìjìyà tí ó dálé bí a ṣe ń hu ìwà àti àwọn ìdánwò míràn nítorí pé wọ́n ti fi ara da ìṣòro sẹ́hín. Èyí jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye tí oníkálukú wa gbà bí a ṣe ń la ìjì já nínú ayé wa..

Ní ìkẹhìn, a sọ fún wa pé ìwà máa ń bí ìrètí. A ní ìrètí fún ọjọ́ iwájú àti fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nítorí pé a mọ̀ pé Olúwa ń ṣọ́ wa. Pọ́ọ̀lù sì sọ pé ìrètí yìí kò ní já wa kulẹ̀.

Níkẹhìn gbogbo àwọn ìjìyà wa ń mú ìrètí kan jáde èyí tí ó sì ń wá sí ìmúṣẹ ní ojoojúmọ́ nínú Jésù.

Kò sí ohun mìíràn tí ó dara jùlọ fún wa láti ṣògo nínú!

Àdúrà: Ọlọ́run mi, o ṣeun tí o lo ìjìyà mi láti jẹ́ kí n jọ Ọmọ Rẹ síi. Ràn mí lọ́wọ́ láti forítì ì, kí n dàgbà nínú ìwà mí, kí n sì rí ìrètì nínú Rẹ. Fún mi ní ìgbàgbọ́ tí yóò mú mi rí i pé Ò ń kọ́ mi láti di ènìyàn gidi síi nípasẹ àwọn ìdánwò mi. O ṣeun fún oore ọ̀fẹ́ Rẹ nígbà tí mo bá kùnà. Àmín.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Finding God's Truth In The Storms Of Life

Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni, a kò bọ́ lọ́wọ́ wàhálà nínú ayé yìí. Ìwé Jòhánù 16:33 ṣe ìlérí wípé wọn yíó wà. Tí o bá ń dojúkọ àwọn ìjì ayé ní báyìí, ètò-ìfọkànsìn yìí wà fún ọ. Ó jẹ́ ìránnilétí ìrètí tí ń mú wa la ìjì líle nínú ìgbésí ayé já. Àti pé tí o kò bá dojúkọ àwọn ìjì kankan ní àkókò yìi, yíó fún ọ ní ìpìlẹ̀ tí yíò ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti la àwọn ìdánwò ọjọ́ iwájú kọjá.

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Vernon Brewer, Olùdásílẹ̀ àti Olùdarí World Help fún ìpèsè ètò Bíbélì yí. Fún àlàyé síwájú sí i, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.worldhelp.net

Àwọn Ètò tó Jẹmọ́ọ