Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ

Don't Give Up

Ọjọ́ 5 nínú 7

Ọjọ́ 5—Jósẹ́fù àti Àwọn Àlá Rẹ̀

Jósẹ́fù jẹ́ ọ̀dọ́ langba tó lá àlá kan. Àlá tó mú kí ìkórìíra tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti ní fun tẹ́lẹ̀ túbọ̀ rinlẹ̀ síi nítorí ó jẹ́ ẹyin lójú bàbá wọn. Àlá náà dá lórí bí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ yóò ti foríbalẹ̀ fun lọ́jọ́ kan.

Pẹ̀lú ǹkan tojú Jósẹ́fù rí lẹ́yìn èyí, díẹ̀ lókù fún àlá náà láti tẹnu bepo. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó mú ìpinnilẹ́mìí dání, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ wùwà aburú síi nípa títà á sí oko-ẹrú. Àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ dà á sí hílàhílo ìmúnisìn àti ìpọ́njú. Gẹ́gẹ́bí ohun ìní ẹlòmíràn, tó wá nínú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀, díẹ̀ lókù kí àlá Jósẹ́fù parun láéláé.

Àmọ́ Jósẹ́fù kò rẹ̀wẹ̀sì tàbí sọ ìrètí nù l'óko ẹrú. Dípò èyí, Jósẹ́fù ṣe ojúṣe rẹ̀ lọ́nà tó dára jùlọ pẹ̀lú làákàyè tí Ọlọ́run yàǹda fún un. Nínú ilé Fọ́tíférì, ó ṣiṣẹ́ kárakára àti wípé ó gbára lé Ọlọ́run. Bó ti ńṣe èyí, ni Ọlọ́run ń bù kún fún un. Lákòókò yí ni a gbe lórí sókè láti máa ṣe àbójútó ìdílé náà tí a sì fi ohun gbogbo sí ìkápá rẹ̀. Ó kọ́ ọgbọ́n nípa ìdarí, ìrẹ̀lẹ̀, àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú àhámọ́ yìí, láì gbàgbé àlá rẹ.

Jósẹ́fù jẹ́ ọkùnrin olóòótọ́ síbẹ̀ nígbà tí aya Fọ́tíférì tọ̀ọ́ wá. Ó fẹ̀sùn kàn án wípé ó fẹ́ tú òhun láṣọ wò èyí sì mú ká a sọ Jósẹ́fù sínú túbú. Ohun tó wá dà bíi ìfàsẹ́yìn padà jásí ìlọsíwájú.

Nínú túbú, Jósẹ́fù bá ojú rere pàdé tí ọ̀gá ẹ̀wọ̀n náà sì fi ṣe alábòójútó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù—lẹ́ẹ̀kan si, a gbe lórí sókè sí ipò adarí. Nínú túbú yìí ni ó ti ṣe alábàápàdé olórí agbọ́tí ọba. Jósẹ́fù ní àǹfààní láti ṣe ìtumọ̀ àlá rẹ̀, èyí tí a mú wá sí ìrántí lẹ́yìn bíi ọdún méjì, nígbà tí ọba pẹ̀lú lá àlá tó nílò ìtumọ̀.

Nígbà tí Jósẹ́fù ṣe ìtumọ̀ àlá ọba nípa ìyàn kan tó ń bọ̀, a gbe lórí sókè sí ipò alákòóso lórí gbogbo ilẹ̀ Íjíbítì. Àlá rẹ̀ padà wá sí ìmúṣẹ! 

Onírúurú ìpèníjà tó lọ́jú, tí kò bá mú ọ̀pọ̀ bíi tirẹ̀ kọsẹ̀, ni Jósẹ́fù ṣe kòńgẹ́ rẹ̀. Àmọ́ ó ní àforítì ó sì ńṣe ojúṣe rẹ̀ lọ́nà tó dára jùlọ pẹ̀lú làákàyè tí Ọlọ́run yàǹda fún un. Fún ìdí èyí, àlá rẹ̀ wá sí ìmúṣẹ, ó sì ṣe àgbàálẹ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún, láì yọ ẹbí rẹ̀ sílẹ̀.

Ọjọ́ 4Ọjọ́ 6

Nípa Ìpèsè yìí

Don't Give Up

Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Brittany Rust fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọ̀wọ lọ sí: http://www.brittanyrust.com