Má Ṣe Rẹ̀wẹ̀sìÀpẹrẹ

Ojó Kejì—Ṣe Àlàyé Ìwà Rẹ́
Nńkan kan nípa ìfaradà ní àgbàrá àràmàǹdà láti sọ ọ́ di ọ̀tún. Ero mi ni wípé o dàbí iná fún òkúta fàdákà, ti nyọ̀ ìdọ̀tí sọ́tọ̀ kúrò tí o tún jẹ́ kí ìwà ẹ̀ni dára. Ìfaradà máa ńsábà lọ pápò pèlú àdánwò àtìpé àdánwò lè máa jó èniyàn.
Ọ̀kán pàtàkì àbájáde ifòrítì títí d'ópìn ní ìwà bí Kristi. Á máa mú ọ di èèyàn tó dára nípa yíyọ ọ́ kúrò nínú ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ àti níní ẹ̀mí rere, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, sùúrù, àti ju gbógbó lọ́, àti máa fi Krísti ṣáájú ohún gbógbo.
Ìwé Róòmù 5 pèsè ìlànà fún ìrìn àjò yìí. Kìí ṣe èyí tó rọrùn àmọ́ o ṣe pàtàkì fún onígbàgbọ. O bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpinnu láti yọ̀ áyọ̀ nínú ìjìyà rẹ. Nígbàtí o bá lè ṣe èyí, wa fojúwíná ìfaradà, èyí tó ńyọrí sí ìwà.
Bi ìwọ́ bá lè rìn ìrìn àjò yìí, ìwé Róòmù fí dájú pé ìwọ́ a ní ìwà. Kìí ṣe níbi nìkan, bákan náà. Fílípì 1 ṣèlérí wípé tí o bá sa eré-ìje naa pèlú afòrítì dé òpin, Ọlọ́run yíó parí iṣẹ́ réré ti O bẹ̀rẹ̀ ní ọdún l'ọ́hùn nìgbàti o yí ọkàn si ọ̀dọ̀ Rẹ.
O kò lè rí ìjé-pípé lónìí, àmọ́ ní ọjọ́ kàn ìwọ yíó dé ilè rẹ̀ —eyi tí Kristi ńṣe ìpèsè rẹ̀—níbi ni ìwọ yíó ti di pípé. Ìwọ yíó rìn, láìsí ẹ̀ṣẹ, ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹdá tí Olórun dá ọ.
Although you may want to give up today, remember that your perseverance will lead to a better version of yourself that resembles Christ more and more over time.
Botilejẹ̀pé o fẹ́ jọ̀wọ́ sílẹ̀ lóní, rántí wípé af'òrítì rẹ yíó yọrí rẹ sí ẹ̀yá dáradára tó túnbọ̀ ńjọ Krísti síwájú sí bí ìgbà ṣe nlọ.
Nípa Ìpèsè yìí

Ṣé ìgbà kan wà tí ó rẹ̀ ọ́ tàbí tí làálàá ayé ti lù ọ́ mọ́lẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó dàbí kí o kọ ohun gbógbó sílẹ̀? Bíbélì kún fọ́fọ́ fún ìgbani-níyànjú láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú àforítì! Ètò kíkà ọlọ́jọ́-méje yìí yóò tù ọ́ lára ní ìmúrasílẹ̀ fún ìrìn-àjò iwájú rẹ.
More