Owe 19:1-3
Owe 19:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère. Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu. Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa.
Pín
Kà Owe 19Owe 19:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú, ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ. Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀, ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà. Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a, ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.
Pín
Kà Owe 19Owe 19:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLúWA.
Pín
Kà Owe 19