Òwe 19:1-3

Òwe 19:1-3 BMYO

Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀, tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnra rẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLúWA.