ÌWÉ ÒWE 19:1-3

ÌWÉ ÒWE 19:1-3 YCE

Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú, ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ. Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀, ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà. Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a, ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú.