Job 15:14-26

Job 15:14-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́, àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo? Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀, mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí, tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi. “Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi; Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ, ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́, Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá. Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára. Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀; nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i. Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápá kan fún idà. Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí. Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun. Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè, Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga, àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.