Job 15:14-26

Job 15:14-26 YBCV

Kili enia ti o fi mọ́? ati ẹniti a tinu obinrin bi ti yio fi ṣe olododo? Kiyesi i, on (Ọlọrun) kò gbẹkẹle awọn ẹni-mimọ́ rẹ̀, ani awọn ọrun kò mọ́ li oju rẹ̀. Ambọtori enia, ẹni irira ati elẽri, ti nmu ẹ̀ṣẹ bi ẹni mu omi. Emi o fi hàn ọ, gbọ́ ti emi, eyi ti emi si ri, on li emi o si sọ. Ti awọn ọlọgbọ́n ti pa ni ìtan lati ọdọ awọn baba wọn wá, ti nwọn kò si fi pamọ́. Awọn ti a fi ilẹ aiye fun nikan, alejo kan kò si là wọn kọja. Enia buburu nṣe lãlã, pẹlu irora li ọjọ rẹ̀ gbogbo, ati iye ọdun li a dá silẹ fun aninilara. Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i. O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà. O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi. Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun. Nitoripe o ti nawọ rẹ̀ jade lodi si Ọlọrun, o si mura rẹ̀ le lodi si Olodumare. O sure, o si fi ẹhin giga kọlu u, ani fi ike-koko apata rẹ̀ ti o nipọn.