JOBU 15:14-26

JOBU 15:14-26 YCE

Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun? Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo? Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli, àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀. Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyan tí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin, tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi! “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ, n óo sọ ohun tí ojú mi rí, (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ, tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́, àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà, àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn). Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà. Etí rẹ̀ kún fún igbe tí ó bani lẹ́rù, ninu ìdẹ̀ra rẹ̀ àwọn apanirun yóo dìde sí i. Kò gbàgbọ́ pé òun lè jáde kúrò ninu òkùnkùn; ati pé dájú, ikú idà ni yóo pa òun. Ó ń wá oúnjẹ káàkiri, ó ń bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’ Òun gan-an sì nìyí, oúnjẹ àwọn igún! Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn ti súnmọ́ tòsí. Ìdààmú ati ìrora dẹ́rùbà á, wọ́n ṣẹgun rẹ̀, bí ọba tí ó múra ogun. Nítorí pé ó ṣíwọ́ sókè sí Ọlọrun, o sì ṣe oríkunkun sí Olodumare, ó ń ṣe oríkunkun sí i, ó sì gbé apata tí ó nípọn lọ́wọ́ láti bá a jà