A. Oni 5:2-3 - Compare All Versions

A. Oni 5:2-3 YBCV (Bibeli Mimọ)

Nitori bi awọn olori ti ṣaju ni Israeli, nitori bi awọn enia ti fi tinutinu wá, ẹ fi ibukún fun OLUWA. Ẹ gbọ́, ẹnyin ọba; ẹ feti nyin silẹ, ẹnyin ọmọ alade; emi, ani emi, o kọrin si OLUWA; emi o kọrin iyìn si OLUWA, Ọlọrun Israeli.

A. Oni 5:2-3 BMYO (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)

“Nítorí bí àwọn olórí ti síwájú ní Israẹli, nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa, ẹ fi ìbùkún fún OLúWA! “Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ fetí yín sílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ-aládé! Èmi yóò kọrin sí OLúWA, èmi yóò kọrin ìyìn sí OLúWA: Ọlọ́run Israẹli.

A. Oni 5:2-3 YCE (Yoruba Bible)

Ẹ fi ìyìn fún OLUWA, nítorí pé, àwọn olórí ni wọ́n ṣiwaju ní Israẹli, àwọn eniyan sì fi tọkàntọkàn fa ara wọn kalẹ̀. Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọba; ẹ tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ìjòyè; OLUWA ni n óo kọrin sí, n óo kọrin dídùn sí OLUWA, Ọlọrun Israẹli.