Isa 28:1-15

Isa 28:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

EGBE ni fun ade igberaga, fun awọn ọmuti Efraimu, ati fun itàna rirọ ti ogo ẹwà rẹ̀, ti o wà lori afonifoji ọlọra ti awọn ti ọti-waini pa. Kiye si i, Oluwa ni ẹnikan alagbara ati onipá, bi ẹfũfu lile, yiyin, ati ìji iparun, bi iṣàn-omi nla àkúnya, yio fi ọwọ́ bì ṣubu sori ilẹ. Ade igberaga, awọn ọmuti Efraimu, li a o fi ẹsẹ tẹ̀ mọlẹ: Ati ogo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọra, yio jẹ itanna rirọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaju igba ìkore; eyiti nigbati ẹniti o ba nwò o ba ri, nigbati o wà li ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbe e mì. Li ọjọ na li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio jẹ ade ogo, ati ade ẹwà fun iyokù awọn enia rẹ̀, Ati ẹmi idajọ fun awọn ẹniti o joko ni idajọ, ati agbara fun awọn ti o le ogun padà si ibode. Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ. Nitori gbogbo tabili li o kún fun ẽbi ati ẹgbin, kò si ibi ti o mọ́. Tani on o kọ́ ni ìmọ? ati tani on o fi oye ẹkọ́ yé? awọn ẹniti a wọ́n li ẹnu-ọmú, ti a si já li ẹnu ọyàn. Nitori aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ; ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: Nitori nipa ète ẹlẹyà ati ni ède miran li on o fi bá enia wọnyi sọ̀rọ. Si ẹniti on wipe, Eyi ni isimi, ẹnyin ìba mu awọn alãrẹ̀ simi; eyi si ni itura: sibẹ nwọn kì yio gbọ́. Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn. Nitorina ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ẹlẹgàn, ti nṣe akoso awọn enia yi ti mbẹ ni Jerusalemu. Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ

Isa 28:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé! Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé! Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára, ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó. Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan, tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun, bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbára tí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè; ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀. Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu. Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdó tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára, yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́, tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè. Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i, yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́. Ní ọjọ́ náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà, fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀. Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè. Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi, ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n. Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii, ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́. Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n; wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́. Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ, gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n? Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún? Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn, àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú? Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni, èyí òfin, tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀. Àwọn tí ó ti wí fún pé: Ìsinmi nìyí, ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi; ìtura nìyí. Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin, èyí òfin tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún, kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́; kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn, kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí, ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan, tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu. Nítorí ẹ wí pé: “A ti bá ikú dá majẹmu, a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn. Nígbà tí jamba bá ń bọ̀, kò ní dé ọ̀dọ̀ wa; nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa, a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”

Isa 28:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún adé ìgbéraga, fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu, àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú àti sí ìlú náà ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀ Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun, gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá, òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀. Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu, ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀. Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀, tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú, yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀, òun a sì mì ín. Ní ọjọ́ náà OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ́ adé tí ó lógo, àti adé tí ó lẹ́wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù. Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́ àti orísun agbára fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì wọ́n pòòrì fún ọtí líle, Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle, wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran, wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá. Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin. “Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú. Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.” Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀ Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀ àwọn tí ó sọ fún wí pé, “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”; àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi” ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀. Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA sí wọn yóò di pé Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú. Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn, tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu. Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀, pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn. Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá, kò le kàn wá lára, nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”