Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efuraimu gbé!
Ẹwà ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí ìtànná náà gbé!
Ìlú tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,
ohun àmúyangàn fún àwọn tí ó mutí yó.
Wò ó! OLUWA ní ẹnìkan,
tí ó lágbára bí ẹ̀fúùfù líle, ati bí ìjì apanirun,
bí afẹ́fẹ́ òjò tí ó lágbára
tí àgbàrá rẹ̀ ṣàn kọjá bèbè;
ẹni náà yóo bì wọ́n lulẹ̀.
Ẹsẹ̀ ni yóo fi tẹ adé ìgbéraga
àwọn ọ̀mùtí ilẹ̀ Efuraimu.
Ògo rẹ̀ tí ń ṣá bí òdòdó
tí ó wà ní òkè àfonífojì dáradára,
yóo dàbí àkọ́so èso ọ̀pọ̀tọ́,
tí ó pọ́n ṣáájú ìgbà ìkórè.
Ẹni tó bá rí i yóo sáré sí i,
yóo ká a, yóo sì jẹ ẹ́.
Ní ọjọ́ náà,
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo jẹ́ adé ògo ati adé ẹwà,
fún àwọn tí ó kù ninu àwọn eniyan rẹ̀.
Yóo jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ ẹ̀tọ́
fún adájọ́ tí ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́,
yóo jẹ́ agbára fún àwọn tí ó ń lé ogun sẹ́yìn lẹ́nu ibodè.
Ọtí waini ń ti àwọn wọnyi,
ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.
Ọtí líle ń ti alufaa ati wolii,
ọtí waini kò jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí wọ́n ń ṣe mọ́.
Ọtí líle ń mú wọn ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n;
wọ́n ń ríran èké, wọ́n ń dájọ́ irọ́.
Nítorí èébì kún orí gbogbo tabili oúnjẹ,
gbogbo ilẹ̀ sì kún fún ìdọ̀tí
Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n?
Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún?
Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn,
àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni,
èyí òfin, tọ̀hún ìlànà.
Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò
láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀.
Àwọn tí ó ti wí fún pé:
Ìsinmi nìyí,
ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi;
ìtura nìyí.
Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.
Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin,
èyí òfin tọ̀hún ìlànà.
Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún,
kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn
kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́;
kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn,
kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí,
ẹ̀yin oníyẹ̀yẹ́ eniyan,
tí ẹ̀ ń ṣe àkóso àwọn eniyan wọnyi ní Jerusalẹmu.
Nítorí ẹ wí pé:
“A ti bá ikú dá majẹmu,
a sì ti bá ibojì ṣe àdéhùn.
Nígbà tí jamba bá ń bọ̀,
kò ní dé ọ̀dọ̀ wa;
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ibi ìsádi wa,
a sì ti fi èké ṣe ibi ààbò.”