Ègbé ni fún adé ìgbéraga,
fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú
àti sí ìlú náà
ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀
Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,
gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,
òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,
tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,
yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè
bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,
òun a sì mì ín.
Ní ọjọ́ náà OLúWA àwọn ọmọ-ogun
yóò jẹ́ adé tí ó lógo,
àti adé tí ó lẹ́wà
fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo
fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́
àti orísun agbára
fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.
Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì
wọ́n pòòrì fún ọtí líle,
Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle
wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì
wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,
wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,
wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì
kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.
“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?
Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?
Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,
sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí
Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”
Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀
Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
àwọn tí ó sọ fún wí pé,
“Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;
àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”
ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA sí wọn yóò di pé
Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ
díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,
wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn
a ó sì gbá wọn mú.
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
kò le kàn wá lára,
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”