Isa 14:24-32
Isa 14:24-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa awọn ọmọ-ogun ti bura, wipe, Lõtọ gẹgẹ bi mo ti gberò, bẹ̃ni yio ri, ati gẹgẹ bi mo ti pinnu, bẹ̃ni yio si duro: Pe, emi o fọ́ awọn ara Assiria ni ilẹ mi, ati lori oke mi li emi o tẹ̀ ẹ mọlẹ labẹ ẹsẹ: nigbana li ajàga rẹ̀ yio kuro lara wọn, ati ẹrù rẹ̀ kuro li ejiká wọn. Eyi ni ipinnu ti a pinnu lori gbogbo aiye: eyi si ni ọwọ́ ti a nà jade lori gbogbo orilẹ-ède. Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun ti pinnu, tani yio si sọ ọ di asan? ọwọ́ rẹ̀ si nà jade, tani yio si dá a padà? Li ọdun ti Ahasi ọba kú, li ọ̀rọ-imọ yi wà. Iwọ máṣe yọ̀, gbogbo Filistia, nitori paṣan ẹniti o nà ọ ṣẹ́; nitori lati inu gbòngbo ejo ni pãmọlẹ kan yio jade wá, irú rẹ̀ yio si jẹ́ ejò iná ti nfò. Akọbi awọn otòṣi yio si jẹ, awọn alaini yio si dubulẹ lailewu; emi o si fi iyàn pa gbòngbo rẹ, on o si pa iyokù rẹ. Hu, iwọ ẹnu-odi; kigbe, iwọ ilu; gbogbo Palestina, iwọ ti di yiyọ́: nitori ẹ̃fin yio ti ariwa jade wá, ẹnikan kì yio si yà ara rẹ̀ kuro lọdọ ẹgbẹ́ rẹ̀. Èsi wo li a o fi fun awọn ikọ̀ orilẹ-ède? Pe, Oluwa ti tẹ̀ Sioni dó, talaka ninu awọn enia rẹ̀ yio si sá wọ̀ inu rẹ̀.
Isa 14:24-32 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní, “Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí; ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ. Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi; n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi. Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi, ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí. Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí, mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu; ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada? Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò? Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini, ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín; nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò, ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà. Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ, aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu. Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ, a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ. Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta. Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá, kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn. Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini? A óo sọ fún wọn pé, “OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀ àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”
Isa 14:24-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró. Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.” Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. Nítorí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà? Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni. Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò. Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn. Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “OLúWA ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”