AISAYA 14:24-32

AISAYA 14:24-32 YCE

OLUWA àwọn ọmọ ogun ti búra, ó ní, “Bí mo ti rò ó bẹ́ẹ̀ ni yóo rí; ohun tí mo pinnu ni yóo sì ṣẹ. Pé n óo pa àwọn ará Asiria run lórí ilẹ̀ mi; n óo sì fẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lórí àwọn òkè mi. Àjàgà rẹ̀ yóo bọ́ kúrò lọ́rùn àwọn eniyan mi, ati ẹrù tí ó dì lé wọn lórí. Ohun tí mo ti pinnu nípa gbogbo ayé nìyí, mo sì ti na ọwọ́ mi sórí orílẹ̀-èdè gbogbo láti jẹ wọ́n níyà.” OLUWA àwọn ọmọ ogun ti pinnu; ta ni ó lè yí ìpinnu rẹ̀ pada? Ó ti dáwọ́lé ohun tí ó fẹ́ ṣe ta ni lè ká a lọ́wọ́ kò? Ọ̀rọ̀ OLUWA tí Aisaya sọ ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Gbogbo ẹ̀yin ará Filistini, ẹ má yọ̀ pé a ti ṣẹ́ ọ̀pá tí ó lù yín; nítorí pé paramọ́lẹ̀ ni yóo yọ jáde láti inú àgékù ejò, ejò tí ń fò sì ni ọmọ rẹ̀ yóo yà. Àkọ́bí talaka yóo rí oúnjẹ jẹ, aláìní yóo sì dùbúlẹ̀ láì léwu. Ṣugbọn n óo fi ìyàn pa àwọn ọmọ ilẹ̀ rẹ, a óo sì fi idà pa àwọn tó kù ní ilẹ̀ rẹ. Máa sọkún, ìwọ ẹnubodè, kí ìwọ ìlú sì figbe ta. Ẹ̀yin ará Filistini, ẹ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí pé àwọn ọmọ ogun kan ń rọ́ bọ̀ bí èéfín, láti ìhà àríwá, kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí ó ń ṣe dìẹ̀dìẹ̀ bọ̀ lẹ́yìn. Èsì wo ni a óo fún àwọn ikọ̀ orílẹ̀-èdè Filistini? A óo sọ fún wọn pé, “OLUWA ti fi ìdí Sioni sọlẹ̀ àwọn tí à ń pọ́n lójú láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi ibẹ̀ ṣe ibi ààbò.”