Isaiah 14:24-32

Isaiah 14:24-32 YCB

OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti búra, “Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí, àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró. Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi, ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀. Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi, ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.” Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé, èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè. Nítorí OLúWA àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà? Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú: Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni. Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò. Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn. Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “OLúWA ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”