Àmì-ìdánimọ̀ YouVersion
BíbélìÀwon ètòÀwon Fídíò
Gba ohun èlò náà
Àṣàyàn Èdè
Ṣe Àwárí

Esek 1:10-11

Esek 1:10-11 Bibeli Mimọ (YBCV)

Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì. Bayi li oju wọn ri: iyẹ́ wọn si nà soke, iyẹ́ meji olukuluku wọn kàn ara wọn, meji si bo ara wọn.

Pín
Kà Esek 1

Esek 1:10-11 Yoruba Bible (YCE)

Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora.

Pín
Kà Esek 1

Esek 1:10-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Báyìí ni ìrísí ojú àwọn ẹ̀dá alààyè yìí: ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú ènìyàn, ní apá ọ̀tún wọn, wọ́n ní ojú kìnnìún ní ìhà ọ̀tún, wọ́n ní ojú màlúù ní ìhà òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n sì tún ní ojú ẹyẹ idì. Báyìí ni àpèjúwe ojú wọ́n. Ìyẹ́ wọn gbé sókè; ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ méjì, ìyẹ́ ọ̀kan sì kan ti èkejì ni ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́, ìyẹ́ méjì tó sì tún bo ara wọn.

Pín
Kà Esek 1
YouVersion

Ńgbà ọ́ níyànjú ó ṣì ń pè ọ́ níjà láti súnmọ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́.

Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Nípaa

Àwọn iṣẹ́

Oluyọọda

Blọ́ọ̀gì

Tè

Àwọn ojú-ìwé tí ó wúlò

Ìrànlọ́wọ́

Fifún ni

Àwon Èyà Bíbélì

Àwọn Bíbélì àfetígbọ́

Àwọn Èdè Bíbélì

Ẹsẹ̀ Bíbélì t'Òní


Isẹ́ Ìránṣẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé

Life.Church
English (US)

©2025 Life.Church / YouVersion

Ìṣe ìdá kọ́ńkó̩Àwon àdéhùn
Ètò Ìpolongo Àwọn Àìléwu
FacebookTwitterInstagramYouTubePinterest

Ilé

Bíbélì

Àwon ètò

Àwon Fídíò