ISIKIẸLI 1:10-11

ISIKIẸLI 1:10-11 YCE

Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora.