Esek 1:10-11

Esek 1:10-11 YBCV

Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì. Bayi li oju wọn ri: iyẹ́ wọn si nà soke, iyẹ́ meji olukuluku wọn kàn ara wọn, meji si bo ara wọn.